Toyin lu ẹṣọ oju popo lalubami, aṣe ayederu ṣọja ni

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii, ni Toyin Ogunlana, ayederu ṣọja, yoo bẹrẹ si i jẹjọ iya manigbagbe to fi jẹ oṣiṣẹ ajọ ẹṣọ oju popo kan, Oje Ọlalekan, lọsẹ to kọja lasiko tiyẹn wa lẹnu iṣẹ.

Awọn ọlọpaa fẹsun kan Toyin, ẹni ọgbọn ọdun, pe o pe ara ẹ ni ọmọ-ogun ilẹ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja, oun atawọn kan si lu Oje nibi ti ọkunrin naa ti n ṣiṣẹ tijọba ran an.

Inspẹkitọ Oriyọmi Akinwale sọ fun kootu Majisreeti-agba to wa niluu Ado-Ekiti ti wọn wọ Toyin lọ pe ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ni wahala naa ṣẹlẹ, ṣe ni olujẹjọ atawọn to ku ẹ ti wọn ti sa lọ bayii si fi waya ina lu ọkunrin naa.

O ni lẹyin ti wọn ṣe e leṣe tọrọ si di tawọn agbofinro lo han pe Toyin ki i ṣe ṣọja, eyi lo si fi jẹbi ẹsun ifiyajẹni ati pipe ara ẹ ni nnkan ti ko jẹ.

Nigba tọrọ kan olujẹjọ, o ni oun ko jẹbi, Amofin Ọlalekan Fagbitẹ si bẹbẹ fun beeli ẹ pẹlu ileri pe yoo maa wa fun gbogbo igbẹjọ.

Majisreeti-agba Ọlanikẹ Adegoke gba beeli afurasi naa pẹlu ẹgbẹrun lọna igba naira (N200,000) ati oniduuro meji, ninu eyi ti ọkan gbọdọ jẹ oṣiṣẹ ijọba onipele kejila.

Leave a Reply