Toyin Saraki ati iyawo gomina Kwara fun obinrin ti awọ ẹyin oju oun atawọn ọmọ rẹ yatọ n’Ilọrin lowo

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Akọṣẹmọṣẹ nipa itọju oju awọn ọmọde to wa ni ileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin, UITH, Dokita Dupẹ Ademọla Popoọla, ti ni ki i ṣe ohun tuntun labẹ ọrun ati nipinlẹ Kwara pe wọn bimọ to gbe ẹyin oju to yatọ waye.

Popoọla, nigba to n ba akọroyin wa sọrọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, lori iṣẹlẹ Risikatu Abdulazeez ti ọkọ rẹ le jade nile nitori bo ṣe bi awọn ọmọ to gbe ẹyin oju to yatọ waye ni o nigba mi-in, o le jẹ arun kan lo fa a, ṣugbọn o ṣee yipada bi onitọhun ba fẹ.

O ni ki i si ṣe ohun teeyan yoo maa bẹru titi debii pe ọkọ yoo maa sa fun iyawo atawọn ọmọ rẹ nitori bi oju wọn ṣe ri.

“Laarin asiko ti mo ti n ṣiṣẹ, mo ti ba iru ẹ bii mẹsan-an pade. Iru ẹ ki i wọpọ, o maa n saaba waye bi ọkan lara awọn obi ba ni i ninu ẹjẹ wọn. Nigba mi-in, ẹ maa ri awọn ti awọ wọn jẹ dudu, ti wọn si maa bi ọmọ to jẹ afin. Ṣugbọn iru ti Risikatu yii, o ti fi han pe ara iya lawọn ọmọ mejeeji ti ko o. Awọn mi-in, oju afin ni wọn maa n gbe waye, to si jẹ pe awọ ara wọn yoo jẹ dudu. O waa ya mi lẹnu bawọn eeyan ṣe n gbe kinni ọhun kiri lori ẹrọ ayelujara. O jẹ ohun to ba mi lọkan jẹ pe ọkọ obinrin naa le e jade nile nitori ọrọ yii.

O tẹsiwaju pe awọn to ba niru ẹyin oju bẹẹ, o ṣee ṣe ki wọn ma le gbọ ọrọ daadaa. Eyi jẹ ara awọn apẹẹrẹ ti wọn le maa ri. Fun idi eyi, ti wọn ba kẹẹfin iru nnkan bẹẹ, o yẹ ki wọn tete lọ silewosan fun itọju.

” Inu mi maa dun ti wọn ba le wa silewosan ka yẹ wọn wo daadaa. Pe ẹyin oju jẹ alawọ omi aro (blue) ko tumọ si nnkan ibanujẹ, koda, nnkan ayọ ni fun ẹbi naa, nitori pe wọn yatọ. Mo le fi awọn ọmọ meje han yin lori foonu mi to jẹ pe bẹẹ ni ẹyin oju wọn ṣe ri.”

Dokita Popoọla ni wọn le lo awo-oju to maa yi awọ ẹyin oju wọn pada, eeyan le yi ẹyin oju rẹ si awọ to ba wu u. O ni to ba wu wọn lati yi awọ oju awọn ọmọ naa pada si ti gbogbo eeyan, ki wọn ko wọn wa silewosan, iṣẹ tawọn yan laayo niyẹn.

O ni meji pere lawọn dokita to n tọju oju ọmọde nipinlẹ Kwara, toun si jẹ ọkan lara wọn. Awọn marundinlogoji lo wa lorilẹ-ede Naijiria.

AKEDE AGBAYE ṣakiyesi pe awọn eeyan loriṣiiriṣii ti n wọ lọ sile awọn Risikatu to wa ladugbo Ayegbami, lagbegbe Alagbado, niluu Ilọrin, lati wo wọn, ati lati ṣaanu fun wọn.

Lara awọn to ti ṣabẹwo si wọn ni Toyin Saraki, iyawo olori ile aṣofin agba tẹlẹ, Dokita Bukọla Saraki. Bakan naa ni iyawo Gomina Kwara, Olufọlakẹ Abdulrazaq.

Saraki labẹ ajọ Well-being Foundation Africa gbe ẹbun ọgọrun-un lọna igba ataabọ naira (#250,000), fun obinrin naa lati ran an lọwọ lori okoowo to ba fẹẹ ṣe, ati lati le tọju awọn ọmọ rẹ mejeeji.

Gẹgẹ bi Toyin Saraki ṣe sọ lori ikanni twitter rẹ, o ni o jẹ ohun to ba oun lọkan jẹ bi ọkọ obinrin naa ṣe pa a ti nitori ọrọ oju naa. O ni ọjọ ọla awọn ọmọ naa ṣe pataki, idi niyi toun fi gbe igbesẹ ọhun lati ro iya wọn lagbara.

Bakan naa ni Olufọlakẹ Abdulrazaq gbe ẹbun owo fun Risikatu.

Awọn aṣoju aya gomina, ninu eyi ti akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Adeniyi Adeyinka wa, ni ijọba ti n ṣeto bawọn ọmọ obinrin naa yoo ṣe pada sileewe, ati bi nnkan yoo ṣe dẹrun fun iya wọn.

Nigba to n sọrọ, Risikat Azeez ni oun atawọn ọmọ oun le riran kedere, awọ oju awọn ko fibi kan di iriran awọn lọwọ rara.

O ni bi oju oun ṣe ri niyẹn ti Wasiu fi fẹ oun, ṣugbọn ṣe lo yiwa rẹ pada nigba toun bi awọn ọmọ mejeeji, nitori bi wọn ṣe gbe awọ ẹyin-oju oun yii waye.

“O wu mi kawọn ọmọ mi kawe. Awọn obi mi gbiyanju niwọnba tagbara wọn mọ lati ran mi lọ sileewe, ṣugbọn mi o le sọ oyinbo, o maa n jẹ ẹdun ọkan fun mi. Akọbi mi ti pe ọmọ ọdun marun-un bayii, ko lọ sileewe ri latigba to ti daye. O wu mi ki wọn lọ sileewe, ki wọn si le sọ oyinbo.”

 

4 thoughts on “Toyin Saraki ati iyawo gomina Kwara fun obinrin ti awọ ẹyin oju oun atawọn ọmọ rẹ yatọ n’Ilọrin lowo

  1. A kìn nú dúpé lówó alásekù , bí kò se alásetán. Kí BBC Yoruba se ìpàdé pèlú Oko àti Ìyàwó láti mó nkan tó dá ìjà sílè, kí wón parí ìjà fún won ,Torí ojó iwájú àwon Omo won. Torí pé Agbó ti enu enìkan dájó, Âgbà òsìkà ni .
    Kí dókítà fi Ojú won sílè bí Olórun se da.

  2. But they interview the man he said he cant carry her anymore that is because of the eyes he left them, so if they settle the matter now he will come back bcos of the money they gave them

  3. There is nothing to settle again. Since thean refuse to take care of the wife and the children. If they settle it again. Thean will only come because of the money and it will be difficult for the wife and the children.
    That is men for you.
    They should just lv the man and continue with the wife and the children.

Leave a Reply