Trump ti sọrọ l’America, o ni gbogbo ibo ti wọn di pata ni wọn gbọdọ tun ka daadaa

Aderounmu Kazeem

Aarẹ ilẹ America, Donald Trump, ti sọ pe o ṣe pataki ki wọn ka gbogbo ibo ti wọn di ninu eto idibo to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to koja yii.

Bo tilẹ jẹ pe pupọ ninu awọn agbegbe ati ipinlẹ ti ẹgbẹ oṣelu The Republican, iyẹn ẹgbẹ oṣelu ti Trump ti jade, ni Joe Biden ti ni ọpọ ibo bayii, sibẹ baba naa ti sọ pe afi ki wọn ka awọn ibo ọhun daadaa.

Ninu ileri to ṣe fawọn eeyan America lo ti sọ pe, “Igbagbọ wa ni pe ko yẹ ka fi irọ bọ ootọ loju fawọn eeyan wa nipa ibo kika ati fifọwọsi pe eto idibo yaranti, bẹẹ ki í se lori eto ibo kan pato bikoṣe lori gbogbo ibo to ba waye.”

Bakan naa lo fi kun un pe, “Latibẹrẹ la ti sọ pe gbogbo ibo ti wọn ba di lọna to tọ la gbọdọ ka, bẹẹ la sọ pe gbogbo ibo to ba ti ni ayederu ninu la o ni i ka rara. Ni bayii, ohun to jẹ iyalẹnu ni bi ẹgbẹ oṣelu alatako ko ṣe fẹẹ tẹle ọna to tọ yii.

“A ṣetan lati fi ofin tọ ọ, eyi tí yoo fun awọn eeyan ilẹ America nigbagbọ ninu ijọba wa. Emi naa ko ni i sinmi lati ja fun yin ati fun orilẹ ede wa.”

Leave a Reply