Tunde, awọn wo ni Agba Ṣakabula?

N ko fẹẹ sọrọ si ọrọ yii rara, ṣugbọn ọrọ naa jo mi lara, nitori ki i ṣe ibi ti mo to Tunde (Pasitọ Tunde Bakare) si ni mo ba a. Ọrọ ti mo gbọ lẹnu aburo wa to n ṣiṣẹ oniwaasu yii ba mi lọkan jẹ kọja bi kinni ọhun ṣe le ye ẹnikẹni. Tunde wa ninu awọn ti mo ti fọkan si pe iranlọwọ nipa iṣọkan Yoruba le ti ọdọ rẹ wa, pe lara awọn kan ti yoo fi awọn ọmọ Yoruba mọna ni. Mo mọ pe ọlọgbọn ni, mo mọ pe onilaakaye ni, mo si ti nigbagbọ pe ko sohun ti yoo maa wa ti yoo tori ẹ ba iran Yoruba jẹ. Ṣugbọn nigba ti ẹni ti a gbojule pe o le mu iṣọkan ba Yoruba ba jade, to fi gbogbo agbaagba to wa nilẹ Yoruba wọlẹ, to pe wọn ni ‘Agbaa Ṣakabula’, ki lo waa tun ku fun wa o? Ki lo ku fun wa gan-an? Ọlọrun mọ pe bi mo ti n wi yii, ko ye mi rara. Bo ba ye mi ni, n ba sọ.

Kinni kan ba wa jẹ, iyẹn naa ni titẹ aṣọ agba mọlẹ – ki awọn ọmode maari agba fin. Awọn ọmọ wa ti wọn ti depo giga, boya nidii oṣelu tabi nidii okoowo wọn, wọn a maa ro pe awọn agbalagba to wa ṣaaju awọn ko lọgbọn kan lori to tiwọn. Bẹẹ ohun ti awọn agba yii n sa fun ni pe wọn ko ni i ba orukọ ara wọn jẹ nitori pe wọn n wa ipo, tabi wọn fẹẹ gba owo lọwo ẹnikan. Bi ọrọ ko ba ye ọmọde, bi awọn agba ba gbe igbesẹ kan, wọn aa bẹrẹ si i bu wọn, wọn yoo ro pe nitori wọn fẹẹ jẹun ni wọn ṣe ṣe ohun ti wọn ṣe. Awọn ti wọn n bu awọn agbalagba Yoruba pe lasiko idibo 2019 wọn ko tẹle Buhari ati awọn eeyan ẹ, ti wọn n bu wọn pe wọn ba Bọla ja pe Bọla fẹẹ ta wa fun Fulani, o daju pe oju wọn aa ti ja a bayii. Ẹni ti Fulani ba ti gbe eeyan ẹ lọ ri, awọn ti Fulani ti pa eeyan wọn, awọn ti wọn ti fipa ṣe iyawo wọn ṣikaṣika, awọn ni wọn le ṣalaye ohun ti Buhari mu waa fun wa.

Awọn agbalagba ti wọn n ta ko Buhari ati awọn Bọla nigba naa, ohun ti wọn ri lo n ṣẹlẹ yii o. Igbagbọ wọn ni pe bi Buhari ba tun wọle, aburu ti awọn Fulani ati Boko Haram n ṣe yoo legba kan si i, nitori Buhari ko ni i ka Fulani lọwọ ko, o da bii pe idunnu rẹ ni ki wọn maa fi iya jẹ awọn ẹya to ku. Ọkunrin kan ti wọn n pe ni Fada Kukah, ẹni ọwọ ọmọ ilẹ Hausa kan bayii, awọn ni wọn lọọ mu Atiku bẹ Ọbasanjọ, lẹyin ti Atiku funra ẹ ti waa ba awọn agba Yoruba yii, to si sọ ohun ti oun maa ṣe, ati awọn ohun ti oun ko ni i ṣe, ti wọn si ba a tọwọ bọ iwe adehun pe to ba wọle, ko ni i fa Yoruba ṣeyin, ko ni i ṣe aburu fun Yoruba, ko si ni i jẹ ki Fulani fiya jẹ awọn eeyan wa. Idi ti awọn agba yii fi gba lati ran Atiku lọwọ pe ko wọle ree, nitori wọn mọ pe inira ni wiwọle ẹlẹẹkeji Buhari maa mu ba Yoruba.

Awọn Bọla mọ ododo yii o, ṣugbọn kaka ki wọn sọ bo ti ri ati bo ṣe jẹ gan-an fawọn ọmọ Yoruba, wọn fun awọn agba yi lorukọ buruku, wọn ni wọn gbowo lọwo Atiku ni, PDP ni wọn, ati bẹẹ bẹẹ lọ.Gbogbo ohun ti ko ṣẹlẹ pata ni wọn n sọ, eyi to si buru nibẹ ni pe awọn eeyan wa gba wọn gbọ, wọn ro pe gbogbo ariwo ti awọn Bọla n pa, ododo ni. Ṣugbọn Ọlọrun ṣe e, gbogbo wa naa la wa laye, ẹni to ba sọ pe iru ijọba ti Naijiria fẹ ni Buhari n ṣe yii, ko sọ bẹẹ ni gbangba lasiko yii, o daju pe ko le fi ara rere lọ. Ẹni to ba sọ pe iru ohun ti Buhari n ṣe fun Yoruba yii lo tọ si Yoruba ni Naijiria, o ku onitọhun, o ku Ọlorun. Awọn ọmọ mi n sọ fun mi pe ṣe mo ti ri awon ọga ọlọpaa tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan.Buhari yan awọn ọga ọlọpaa tuntun si ipo giga. Ṣugbọn ohun ti wọn ṣe nibi agbega yii buru jai.

Ninu awọn ọga agba metadinlogoji (37) ti Buhari yan, awọn Hausa Funlani lati ọdọ tiwọn ko mẹrinlelogun (24), wọn fun Yoruba ni meje (7), wọn fun awọn Naija-Delta ni marun-un (5), wọn si fun awọn Ibo ni ẹyo kan (1). Bi Buhari ṣe n ṣe ohun gbogbo ree, ko si ohun to kan an kan Naijiria ijọba awọn Hausa-Fulani lo n ṣe. Ọrọ naa ka Fada Kukah ti mo sọrọ ẹ lẹẹkan lara to fi sọ pe ko si olori ijọba Naijiria to huwa ẹlẹyamẹya to to ti Buhari yii ri, ati pe bo ba jẹ ki i ṣe Hausa-Fulani ni, awọn ṣọja iba ti gbajọba lọwọ ẹ tipẹ. Awọn ẹni ti ọrọ ko ye bẹrẹ si i bu Kukah lati igba to ti mu Atiku lọọ bẹ Ọbasanjọ, wọn ko mọ ohun ti Kukah ri, wọn ko mọ pe Kukah ri i pe Buhari maa sọ Naijiria di ahoro gbẹyin, tabi ko sọ ọ di orilẹ-ede awọn Fulani nikan, nibi ti awọn Fulani aa ti maa pa ẹni ti wọn ba fẹ, ti wọn aa si maa gba ilu ati ilẹ onilẹ bo ba ti ṣe wu wọn, ti Buhari o si ni i sọ pe ohun ti wọn n ṣe ko dara.

Awọn ohun ti awọn onilaakaye agbaagba Yoruba ri lati ọjọ to pẹ ree, ti wọn fi sọ pe Buhari ko daa, ki i ṣe eeyan ti yoo ṣejoba alaafia, ijọba itajẹsilẹ ni yoo ṣe. Ati pe bi Atiku ba wọle, ibajẹ tirẹ ko ni i to ti Buhari yii, nitori oun o ṣaa ni i fa wa le awọn Fulani lọwọ. Atiku ni awọn ọmọ ti wọn jẹ Yoruba, o ni awọn ọmọ ti wọn jẹ Ibo, o si ni awọn ọmọ ti wọn jẹ Hausa pẹlu awọn iya wọn, eleyii ko ni i jẹ ko gbe aye Naijiria le Fulani lọwọ, koda ko ko owo jẹ bi awọn kan ti n sọ pe o fẹẹ waa ṣe. Buhari ti wọn ni ko ni i ko owo jẹ naa ree o! Buhari ti wọn ni ki i ṣe ẹlẹyamẹya naa ree o! Gbogbo awọn Bọla ti wọn ko wa si wahala yii ko sọrọ mọ bayii, bi awọn ṣe fẹẹ pada gba ijọba lọwọ Buhari lo ku to jẹ wọn logun, awọn naa fẹẹ waa ṣejọba tiwọn, wọn ko si ronu nijọ kan pe ṣe Naijiria yii yoo wa titi di ọdun 2023 ti awọn n le yii, bo ba ṣe pe bi Buhari ti n ṣe yii naa lo n ṣe.

Ohun to wa n dun mi ni pe Tunde wa ninu awọn to mọ ododo ati bi ọrọ ti jẹ. Boya Tunde si ti gbagbe ohun to sọ fun awa agbaagba kan nipa Bọla lẹyin 2011, nigba ti Bọla sọ fun un pe ko jẹ ki oun ṣe igbakeji Buhari, ki wọn jọ tọwọ bọ iwe adehun, ki oun Tunde yii kọwe fi ipo silẹ lai ti i di igbakeji Buhari rara, pe ti oun ba kọwe fi ipo silẹ, iwe aa wa lọwọ oun Tinubu, bi Buhari ba ti waa wọle, awọn aa gbe lẹta naa jade, oun Bọla aa waa di igbakeji Buhari. Ṣe Tunde gbagbe ọrọ yii ati awọn to sọ ọ fun ni. Tabi Tunde ko ranti ohun to sọ pe Bọla sọ foun nigba ti oun ni awọn Kristẹni ko ni i gba pe ki Musulumi meji, iyẹn oun Bọla ati Buhari, maa ṣejọba le wọn lori, ti Bọla sọ fun un pe gbogbo awọn olori ẹsin Kristẹni ni Naijiria loun n sanwo oṣu fun, oun ti ra wọn pa debii pe ko sẹni to maa sọrọ to ba ti jẹ orukọ oun ni wọn da. Ṣe Tunde ti gbagbe eleyii ni!

Ṣe Tunde ti gbagbe lọdun to kọja, awọn agbalagba ti wọn jọ ṣepade ni ilu Ikẹnnẹ, awọn agba Yoruba to n bu yii ma ni! O ti gbagbe ohun to sọ fun wọn nipade naa ni! Ipade ti wọn ṣe nile Awolọwọ ni mo n wi n’Ikẹnnẹ o. Ṣe Tunde ko ranti ohun ti oun sọ fun wọn nibẹ mọ ni. Kin ni wọn waa ṣe fun un o! Ki lawọn agbaagba Yoruba ṣe fun un ti wọn fi di agba ṣakabula. Lara awọn aburo wa ti a n ro pe a oo fa ilẹ Yoruba le lọwọ naa ree o! Lara awọn aṣaaju ọdọ ti a n ro pe wọn le tun nnkan ṣe. Njẹ ki i ṣe pe wọn maa tubọ ba nnkan jẹ bayii!

Tunde, awọn wo ni agba Ṣakabula? Ọrọ iran Yoruba yii ma fẹẹ su mi o! Tabi iru awọn eeyan wo ni Ọlorun da saye yii. Nigba ti olori ẹsin pataki bayii ba tori ipo to n wa, tabi ohun to fẹẹ gba, to ba gbogbo agbalagba ilẹ Yoruba lorukọ jẹ to bayii!

Awọn ibeere pataki kan wa ti mo fẹ ki Tunde da mi lohun lori ọrọ Bọla ati lori ọro oun paapaa. Ẹyin ti ẹ n lọ si ṣọọṣi ẹ, ẹ sọ fun un ko maa reti mi!

Leave a Reply