Tunde Bakare loun ti bẹrẹ ipolongo atunto Naijiria lakọtun

Faith Adebọla, Eko

 Oludasilẹ ati adari Citadel Global Community Church, ti wọn n pe ni ṣọọṣi Latter Rain tẹlẹ, Pasitọ Tunde Bakare, ti kede pe oun ti ṣefilọlẹ igbesẹ lati ri i daju pe atunto waye ni Naijiria, o ni ẹgbẹ N4N loun maa lo lati mu ki eyi ṣee ṣe.

Bakare sọrọ yii di mimọ ninu ọrọ kan to sọ ni ṣọọṣi rẹ lọjọ Aiku, Sannde, lori ipo ti Naijiria wa lasiko yii.

Bakare ni: “O ti to asiko wayi fawọn ọmọ Naijiria lati gba orileede wọn pada, o si da mi loju tadaa pe ijọba maa yipada lọdun 2023.

Ẹgbẹ tuntun naa la oo maa pe ni ‘New Nigeria Progressive Movement,’ oun la maa fi ja lati fidi iṣọkan ati iṣejọba gidi mulẹ lorileede yii.

Koda laarin awọn ti wọn n leri pe awọn maa ṣe atunto tawọn ba depo oṣelu, ọrọ wọn o jọra, ajọṣe to dan mọran ko si si laarin wọn debi ti wọn aa fi le pawọ-pọ, panu-pọ jiroro bi Naijiria ṣe le bọ soju ọna aṣeyọri.

Eyi lo fi jẹ pe ti asiko idibo ba ti n sun mọle, ẹlẹya Naijiria maa n yọ, gbogbo ọrọ tawọn kan ti n sọ ṣaaju ki i ta mọ, kedere lo maa n han pe orileede to n ṣubu lọ la wa.

Ẹyin ọmọ Naijiria ẹlẹgbẹ mi, mo n kede fun yin bayii pe asiko ti to fun awọn to nifẹẹ itẹsiwaju tootọ lati dide, iran-ran oṣelu ti to gẹẹ, o ti to asiko lati gba orileede wa pada. A maa gbe eto kalẹ to maa jẹ ki ijiroro apapọ waye, ki i ṣe ọrọ idibo o, ṣugbọn a fẹẹ bẹrẹ si i fi ipilẹ lelẹ fun atunto orileede yii.

Lati ile de ile, ilu nla si abule oko, gbogbo kọrọ la maa de pẹlu eto wa, koko mẹta pere naa ni eto wa da le lori, atunto, atunto ati atunto ni. Atunto fun Iṣọkan Naijiria ni (Restructuring for United Nigeria).

Mo maa ṣiwaju eto yii, emi ni ma a dari ẹ. A maa darapọ mọ awọn orileede agbaye kan, gbogbo ẹya to wa kaakiri la maa ko mọra, a si jọ maa ṣiṣẹ papọ lori atunto ọhun ni titi ti Naijiria yoo fi di orileede amuyangan fun ẹnikọọkan wa.”

Leave a Reply