Tunde Kelani ṣafihan fiimu itan igbesi aye Ayinla Ọmọwura

Faith Adebọla

Ẹsẹ ko gbero lọjọ Aiku, Sannde yii, nibi ti wọn ti ko fiimu tuntun kan ti wọn pe akọle ẹ ni ‘Ayinla’ jade bii ọmọ tuntun, tawọn eeyan si n gboṣuba fun Tunde Kelani atawọn oṣere to kopa ninu fiimu to fitan nla balẹ ọhun.

Lati nnkan bii aago mẹrin irọlẹ lawọn eeyan ti n de leni eji si Gbọngan igbalejo ile sinima EbonyLife Place, to wa ni Victoria Island, l’Erekuṣu Eko, lọjọ naa, nigba ti yoo si fi di aago mẹfa irọlẹ ti eto naa yoo bẹrẹ, fọfọọfọ ni gbọngan naa ku fun ero rẹpẹtẹ.

Fiimu yii ni wọn fi sọ itan igbesi aye ilu-mọ-ọn-ka akọrin Apala ọmọ bibi ilu Abẹokuta nni, Oloogbe Ayinla Ọmọwura, ti inagijẹ rẹ n jẹ Eegunmọgaji.

Fiimu naa sọ nipa ibẹrẹ igbe aye ‘alujọọnu olorin’ yii, bo ṣe di onirawọ, bo ṣe maa n ri imisi orin rẹ gba, titi kan bi iyawo pupọ ṣe wa lọọdẹ rẹ, bo ṣe gbero lati gbe orin Apala lọ siluu oyinbo.

Fiimu naa tun taṣiiri ohun to fa ija laarin oun ati manija ẹ nigba naa lọhun-un, ati bi ọrọ iku rẹ ṣe waye gan-an.

Ọpọ awọn oṣere ilẹ wa, titi kan awọn to kopa ninu fiimu naa to pesẹ sibi ayẹyẹ ọhun ni Kunle Afọlayan, to kopa ọga ejẹnti to fẹẹ gbe Ayinla ati orin rẹ lọ si London, Lateef Adedimeji, to kopa Ayinla Ọmọwura, Debọ Adedayọ (Mista Makaroni), to kopa Maneja Ayinla.

Awọn mi-in to tun wa nikalẹ nibi afihan sinima naa ni Toyin Abraham (Iya Ire), Mercy Aigbe, Fẹmi Branch, Jumọke Ọdetọla, Bimbọ Ademoye, Tunde Kelani, to jẹ alaṣẹ ileeṣẹ Mainframe Productions to ya simima yii, ati awọn ọjẹwẹwẹ onitiata mi-in.

Banki First Bank ati ileeṣẹ Nigerian Breweries to n pọn ọti bia Trophy lo ṣonigbọwọ sinima ọhun, wọn si ṣeto ipapanu ati ọti lọfẹẹ tawọn eeyan fi gbadun ara wọn.

Bakan naa ni awọn eeyan meji, ọkunrin kan ati obinrin kan jẹ ẹbun ẹni to mura daadaa ju lọ, ọkọọkan wọn ni wọn fun niwee sọwedowo ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (#500,000) gẹgẹ bii ẹbun ti wọn jẹ.

Nigba ti akoko to lati ṣafihan fiimu naa, gbọngan iworan nla marun-un ọtọọtọ ni wọn ti ṣafihan rẹ.

Ṣaaju ati lẹyin ti wọn ṣafihan fiimu naa tan, ọpọ awọn oṣere atawọn ero to waa woran sọrọ iwuri ati idunnu nipa fiimu yii, eyi lawọn ohun ti wọn sọ:

Leave a Reply