Tunde lu ileeṣẹ kan ni jibiti owo nla, lo ba dero kootu

Florence Babaṣọla

Oṣiṣẹ ileeṣẹ Lexican Imvestments Limited, ni Ọmọle Layout, niluu Ileefẹ, ni Bamidele Tunde, ṣugbọn o ti lu ileeṣẹ naa ni jibiti ọkẹ aimọye miliọnu naira ko too di pe aṣiri rẹ tu.

Nigba ti aṣiri tu ni wọn fa a le ọlọpaa lọwọ, lẹyin to jẹwọ ninu akọsilẹ rẹ ni wọn taari rẹ lọ sile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ileefẹ lọsẹ to kọja.

Agbẹjọro to wa lati ileeṣẹ eto idajọ nipinlẹ Ọṣun, Abiọdun Badiora, ṣalaye pe ṣe ni Tunde ṣe ayederu risiiti pẹlu nọmba 538743, 558744, 538739, 538570, 538572 ati 538573. Risiiti yii la gbọ pe o fi ji owo to to miliọnu mẹrindinlọgbọn naira (#26m) laarin oṣu kin-in-ni ọdun 2019 ati oṣu kẹfa.

Ẹsun mẹtala ni wọn fi kan Tunde, lara wọn si ni ẹsun ole jija ati jibiti lilu, ṣugbọn ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn naa sọ pe oun ko jẹbi.

Adajọ A. I. Oyebadejọ ko faaye beeli silẹ fun olujẹjọ latari pe jibiti owo to lu pọ ju.

O paṣẹ pe ki wọn lọọ fi i pamọ sọgba ẹwọn ilu Ileefẹ titi di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ti wọn yoo sọrọ lori beeli rẹ.

Ninu iroyin mi-in, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti wọ Hammed Abiọdun lọ sile-ẹjọ Majisreeti ilu Oṣogbo lori ẹsun ole jija.

Agbefọba, Adeoye Kayọde, ṣalaye pe olujẹjọ atawọn kan huwa naa loju ọna Ikirun si Iragbiji, lọjọ kejilelogun, oṣu kẹta, ọdun yii, laago mẹsan-an alẹ.

Ṣe ni wọn ja ọkunrin kan, Arole Hammed, lole owo to to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (#500,000). Nigba ti olujẹjọ sọ pe oun ko jẹbi ni agbẹjọro rẹ, Okobe Najite, bẹ ile-ẹjọ lati fun un ni beeli.

Majisreeti Abayọmi Ajala fun Hammed ni beeli pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (#500,000) ati oniduuro meji.

Leave a Reply