Udoka ji mọto ọga ẹ gbe l’Ekoo, ipinlẹ Imo lo n gbe e lọ tọwọ fi tẹ ẹ

Faith Adebọla, Eko

 Ọkunrin kan, Ibe George Udoka, lẹ n wo ninu fọto yii, ọkọ ayọkẹlẹ ọga to n ṣe dẹrẹba fun lo ki mọlẹ, o wa mọto ọhun lọ sipinlẹ Imo fawọn to fẹẹ ta a ni gbanjo fun, ṣugbọn oju ọna lọwọ awọn agbofinro ti tẹ ẹ.

CSP Olumuyiwa Adejọbi, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, lo fọrọ naa to ALAROYE leti l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, o ni nnkan bii aago kan ọsan ọjọ kẹrin, oṣu karun-un yii, ni Abilekọ Ibironkẹ Akinọla sare jannajanna de teṣan ọlọpaa Idimu, o waa fẹjọ sun pe oun o ri dẹrẹba oun pẹlu mọto mọ, ẹya Toyota Corona alawọ buluu lo pe mọto ọhun ti nọmba rẹ jẹ ABC 801 FU, o loun ti wa wọn titi, gbogbo ibi toun mọ to le wa loun ti de, ko sẹni to gburoo ẹ rara, ki wọn jọwọ, ran oun lọwọ.

O ni gbogbo nọmba foonu ẹ lo ti lu pa, gbogbo ibi to loun n gbe ti wọn le wa a si wọn de, ko sẹni to ri awakọ ọran yii.

Wọn ni bawo ni mọto ṣe de ọwọ Udoka nigba ti ọga ẹ o si nibẹ, obinrin naa si ṣalaye pe niṣe loun ni ko gbe mọto lọ sọdọ mẹkaniiki ki wọn le ba oun wo nnkan to n pariwo woroworo labẹ ọkọ naa, oun si ti pe mẹkaniiki lori aago pe dẹrẹba oun maa too de ọdọ ẹ, afi bo ṣe di pe mẹkaniiki ko foju kan mọto ati dẹrẹba, bẹẹ loun naa o si ri wọn.

Loju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa ti bẹrẹ si i fi ipe alatagba sọwọ sawọn ọlọpaa to ku lori redio wọn, kia si lawọn ọlọpaa kaakiri teṣan wọn ti n dọdẹ dẹrẹba naa, wọn si n fimu finlẹ nipa ẹ.

Ọjọ kẹta lẹyin naa ti afurasi ọdaran naa wa mọto ọhun de ilu Benin, nipinlẹ Edo, lo kan awọn ọlọpaa lọna, wọn si da a duro, wọn ni ko ko iwe ọkọ wa. Wọn bi i leere pe ta lo ni mọto, o lọgaa oun torukọ ẹ wa ninu iwe toun ko fun wọn ni, ati pe ọga naa lo ran oun niṣẹ lọ si Imo. Ni wọn ba ni ko pe ọga ẹ lori aago, kawọn le jẹrii ohun to sọ, n lakara ba tu sepo, wọn si fi pampẹ ọba gbe e.

Lasiko iwadii, wọn lo jẹwọ pe oun ji mọto naa gbe ni, oun fẹẹ lọọ ta a si ipinlẹ Imo ni, o loun ti pe awọn kan pe ki wọn ba oun wa ẹni to maa ra mọto naa silẹ tori oun o fẹ ko pẹ nilẹ rara.

Ọjọ kẹta ni wọn fi oun ati mọto onimọto to ji ọhun ṣọwọ si Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, CP Hakeem Odumosu.

Ni bayii, awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lẹka iwa ọdaran ni Panti, Yaba, ti ki Udoka kaabọ sọdọ wọn, o si ti n ran wọn lọwọ lori awọn ibeere ti wọn ni fun un. Wọn ni ko ni i pẹ foju bale-ẹjọ.

CAPTION

Leave a Reply