Umar Sadiq dero ileewosan lẹyin ija ni Russia

Oluyinka Soyemi

Abẹṣẹ-ku-bii-ojo ọmọ ilẹ wa, Umar Sadiq, ti n gba itọju nileeowsan bayii lẹyin ija to ja pẹlu Fyodor Chudinov nilẹ Russia.

Ẹni ọdun mejilelọgbọn naa ni wọn sọ pe o pọ ẹjẹ lẹyin to fidi-rẹmi nipele to gbẹyin ija WBA Gold Belt, eyi lo si jẹ ki wọn sare gbe e lọ si ọsibitu, ṣugbọn ara ẹ ti ya daadaa bayii.

Umar to ti di ọmọ ilẹ Britain lo gba lati ja ija ọhun lasiko to kere jọjọ siye ọjọ to yẹ ko fi gbaradi, ṣugbọn o ni ko sewu, oun yoo koju Fyodor.

Ija to waye gbẹyin yii ni igba keji ti Umar yoo fidi-rẹmi ninu ija mejila to ti ja, ninu mẹwaa to si ti jawe olubori, igba mẹfa lo fi ẹṣẹ gbe awọn alatako ẹ ṣubu.

Ilẹ Naijiria ni wọn bi Umar si ko too kọja si Britain, ọdun 2017 lo si ja ija akọkọ lagbo ẹṣẹ kikan.

Leave a Reply