Usman Alkali Baba di ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa

Faith Adebọla

Igbimọ to n ṣakoso ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa (Nigeria Police Council), ati Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọ lu Usman Alkali Baba lati di ọga ọlọpaa patapata, iyẹn Inspẹkitọ Jẹnẹra (IGP) awọn ọlọpaa ilẹ wa.

Owurọ ọjọ Ẹti, Furaidee yii, ni Buhari ṣepade pẹlu igbimọ ọhun nile ijọba l’Abuja, lati fẹnu ko lori iyansipo Usman Baba, eyi ti Buhari ṣe lọjọ kẹfa, oṣu kẹrin, ọdun yii.

Minisita to n ri si ọrọ awọn ọlọpaa, Alaaji Maigari Dingyadi, jabọ fawọn oniroyin lẹyin ipade naa pe Aarẹ Buhari ati ileeṣẹ ọlọpaa fimọ ṣọkan lori iyansipo naa, wọn si ti sọ Usman Baba di IG, o ti kuro nipo adele ọga agba to ti wa latigba ti wọn ti kọkọ yan an sipo.

Usman Baba, ẹni ti wọn bi lọjọ kẹfa, oṣu kẹta, ọdun 1966, niluu Geidam, nipinlẹ Yobe, lo bọ sipo ọga agba patapata ileeṣẹ ọlọpaa lẹyin ti Mohammed Adamu fẹyinti nipo ọhun loṣu keji, ọdun yii, ki Aarẹ too fa akoko ifẹyinti rẹ gun siwaju di ọjọ karun-un, oṣu kẹrin.

Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹta, ọdun 1988, lo wọṣẹ ọlọpaa, oun si ni ẹni kọkandinlogun ọmọ Naijiria ti yoo di ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa latigba ti orileede wa ti gba ominira.

Leave a Reply