Usman beere owo lọwọ baba ẹ, iyẹn ko fun un, lo ba gun un lọbẹ nidodo

Ọlawale Ọlawale, Ibadan

Ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun) kan, Usman Omidiran, ti n kawọ pọnyin rojọ nile-ẹjọ Majisireeti to wa n’Iyaganku, n’Ibadan, nipa bo ṣe gbiyanju lati dẹmi-in baba to bi i lọmọ legbodo.

ALAROYE gbọ pe ede aiyede yii waye nigba ti baba ẹni ọdun marundinlaaadọrin yii, Jimoh, kọ lati fun Usman lowo to beere fun, n lọmọ yii ba fa ibinu yọ, to si fọbẹ gun baba to bi i saaye nidodo ati lapa osi.

Ṣaaju lawọn ọlọpaa ti sọ olujẹjọ naa to jẹ olugbe ilu Igangan, nipinlẹ Ọyọ, satimọle ni teṣan wọn lọhun-un, ki wọn too waa foju ẹ bale-ẹjọ.

Agbofinro to ṣoju CP Ngozi Onadeko ni kootu, Ripẹtọ Olufẹmi Omilana, sọ niwaju ile-ẹjọ pe lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kin-in-ni, ni deede aago mẹfa aabọ irọlẹ ni Usman gun baba ẹ lọbẹ nigba ti tọhun ko rowo to beere fun un.

Ripẹtọ ọlọpaa yii tẹsiwaju pe afurasi yii jẹbi ẹsun iwa ọdaran labẹ ofin ipinlẹ Ọyọ tọdun 2000.

Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti naa, Onidaajọ Munirat-Giwa Babalọla, ko faaye silẹ lati gbọ awijare  afurasi ọdaran yii.

O waa paṣẹ pe ki wọn fi Usman pamọ sinu ahamọ ọgba ẹwọn to wa Labolongo, niluu Ọyọ, titi tile-ẹjọ naa yoo fi ri imọran gba lọwọ igbimọ to n ri si ọrọ iwadii ẹsun ọdaran nileeṣẹ eto idajọ ipinle Ọyọ.

O waa sun igbẹjọ si ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹta, ọdun 2022 yii.

Leave a Reply