Ewurẹ mẹwaa lawọn ọrẹ meji yii lọọ ji gbe niluu igẹmọ-Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Iwadii ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti bẹrẹ lori awọn afurasi meji kan tọwọ tẹ pe wọn ji ewurẹ niluu Igbemọ-Ekiti, nijọba ibilẹ Irẹpọdun/Ifẹlodun.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii lawọn ọlọpaa gbọ si iṣẹlẹ naa lẹyin tawọn araalu mu awọn eeyan ọhun pẹlu mọto Nissan Primera kan ti wọn ko awọn ewurẹ naa si.

Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, sọ ọ di mimọ pe ni nnkan bii aago meje aarọ lawọn ọlọpaa tẹsan Iworoko-Ekiti gba ipe kan latọdọ awọn ọdẹ ilu Igbemọ-Ekiti pe ọwọ tẹ awọn meji kan ti wọn ko ewurẹ mẹwaa sinu ọkọ ti alaye wọn si mu ifura dani.

Abutu ni, ‘’Bi ọga ọlọpaa teṣan naa ṣe gbọ lo ko awọn ọtẹlẹmuyẹ atawọn ọlọpaa mi-in lọ sibi iṣẹlẹ naa, wọn si ko awọn afurasi ọhun wa si teṣan wọn.

‘’Lasiko iwadii lawọn afurasi yii sọ pe loootọ lawọn ji awọn ewurẹ naa gbe, ati pe ilu Isẹ-Ekiti, nijọba ibilẹ Isẹ/Ọrun, lawọn ti n ko wọn bọ, bẹẹ lawọn n lọ Ado-Ekiti lati ta wọn.’’

Alukoro naa ni ooru tiẹ ti mu marun-un ninu awọn ewurẹ naa pa ninu buutu ti wọn ko wọn si, marun-un pere lo si wa laaye lasiko tọwọ tẹ awọn to ji wọn.

O waa dupẹ lọwọ awọn ọdẹ to mu awọn afurasi naa, bẹẹ lo ni ile-ẹjọ lawọn mejeeji yoo ti ṣalaye ra wọn fun ijọba laipẹ.

Leave a Reply