Wahala APC l’Ekiti n le si i, wọn ti yọ Fayẹmi ninu ẹgbẹ

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

O jọ pe wahala inu ẹgbẹ oṣelu APC n fojoojumọ le si i ni bi awọn kan ninu ẹgbẹ oṣelu naa ṣe paṣẹ pe ki Gomina Fayẹmi fi ẹgbẹ ọhun silẹ fun igba diẹ.

Ko ti i ju wakati mẹrinlelogun lọ ti ẹgbẹ oṣelu naa ni ki ana Aṣiwaju Bọla Tinubu, Ọnarebu Oyetunji Ojo, pẹlu Babafẹmi Ojudu atawọn eeyan mẹjọ mi-in maa lọ sile wọn, ti eyi naa fi ṣẹlẹ. Ohun tawọn Ojudu si sọ nigba ti wọn le wọn ni pe awada lasan ni, digbi lawọn ṣi wa ninu ẹgbẹ naa.

Lara awọn to fọwọ si iwe gbelẹ-ẹ ti wọn kọ si gomina yii ni Sẹnetọ Tony Adeniyi, Sẹnatọ Babafẹmi Ojudu, Dayọ Adeyeye, Oyetunji Ojo atawọn mi-in

Ẹsun ti wọn fi kan Fayemi ni pe, o gbe awọn igbesẹ kan to tako ẹgbẹ ọhun, paapaa lori ọrọ ibo to waye l’Edo. Wọn ni Fayemi naa wa lara awọn gomina to fẹyin pọn Godwin Obaseki to fi dojuti ẹgbẹ APC l’Edo.

Ṣa o, minisita feto irinna ọkọ ofurufu nigba kan, Fẹmi Fani-Kayọde, ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ awọn to yọ Fayẹmi lẹgbẹ. O loun mọ pe nitori ti oun lọọ ki gomina naa nigba to ku ọjọ marun-un ti eto idibo Edo yoo waye ni wọn ṣe gbogun ti i. Ọkunrin yii fi kun un pe ọrọ to jẹ mọ orilẹ-ede yii lawọn jọ sọ, ati pe bii ọgbọn ọdun ree ti awọn ti jọ n ṣọrẹ, bẹẹ lọrọ ẹgbẹ oṣelu ko le sọ awọn dọta laelae.

Oriṣiiriṣii wahala to wa ninu ẹgbẹ oṣelu APC l’Ekiti niyẹn o, bẹẹ lẹgbẹ naa ti pin si meji bayii, ti awọn kan n tẹle Gomina Fayẹmi, ti apa keji si jẹ tawọn Ojudu ati ana Asiwaju Bọla Tinubu pẹlu awọn eeyan kan.

Leave a Reply