Wahala Arẹgbẹṣọla ati Oyetọla: Ẹgbẹ igbimọ agba APC l’Ọṣun sọ pe ilẹkun awọn ṣi silẹ f’Omiṣore

Florence Babaṣọla

Pẹlu bi wahala aarin Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ati Gomina Gboyega Oyetọla ṣe n fojoojumọ gbilẹ si i, awọn Igbimọ-Agba Ọṣun ninu ẹgbẹ naa ti sọ pe gbayau nilẹkun ẹgbẹ ṣi silẹ fun ẹnikẹni to ba fẹẹ darapọ mọ awọn.

Lopin oṣẹ to kọja ni Arẹgbẹṣọla sọ niluu Ileṣa, lasiko to lọọ forukọsilẹ pe awọn apaayan, abanilorukọjẹ, janduku atawọn ti ko ṣee ba to ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC, to si kilọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ ko gbọdọ faaye gba awọn ti wọn ko naani Oloogbe Bọla Ige lati dipo adari mu.

Ọrọ yii lawọn eeyan ro papọ ti wọn fi n sọ pe Sẹnatọ Iyiọla Omiṣore ti Gomina Gboyega Oyetọla ṣẹṣẹ fa oju rẹ mọra latinu ẹgbẹ oṣelu SDP si ẹgbẹ APC ni Arẹgbẹṣọla n ba wi.

Latigba naa si ni oniruuru wahala ti n ṣẹlẹ, bi awọn alatilẹyin Omiṣore ṣe n bu Arẹgbẹṣọla ni awọn ololufẹ Oyetọla naa n sọko ọrọ si i, ṣugbọn esi kan ṣoṣo ti awọn ọmọ Arẹgbẹṣọla n fọ ni pe ara lo n fu gbogbo wọn, nitori ọga awọn ko darukọ ẹnikẹni ninu ọrọ to sọ n’Ileṣa.

Lati le bomi pana ọrọ yii ni alaga igbimọ agba Ọṣun ninu ẹgbẹ APC, Ẹnjinnia Ṣọla Akinwumi ṣe ṣalaye fun ALAROYE pe niwọn igba ti iwe-ofin orileede wa ti faaye silẹ fun ẹnikẹni to ba ti pe iye ọjọ-ori kan lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu, ko sẹni ti ko le darapọ mọ ẹgbẹ awọn.

Oloye Akinwumi sọ pe teeyan ko ba fẹẹ tan ara rẹ jẹ, ipa takuntakun ni Omisore ko ninu ọrọ inawo ẹgbẹ AD ninu idibo ọdun 1998 si ọdun 1999, eleyii to tumọ si pe ki i ṣe ajeji ninu ẹgbẹ, ọmọwale ni.

O ni bi awọn lookọlookọ ninu oṣelu ipinlẹ Ọṣun ṣe n darapọ mọ ẹgbẹ APC lasiko iforukọsilẹ yii fihan pe aṣaaju rere ni Gomina Adegboyega Oyetọla, ẹni to tun jẹ adari ẹgbẹ nibaamu pẹlu ilana ofin ẹgbẹ ti ọdun 2014.

Akinwumi ṣalaye pe iwa suuru, ikonimọra, ṣiṣe ohun gbogbo letoleto, nini akoyawọ ati gbigba imọran, ti gomina ni, n ran ẹgbẹ naa lọwọ loorekoore, tigbagbọ si wa pe yoo jẹ ki aṣeyọri pupọ ba ẹgbẹ naa ninu idibo to n bọ.

O ni ki gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lọọ farabalẹ daadaa, ki wọn ma ṣe faaye gba ikunsinu kankan lori ọrọ iforukọsilẹ to n lọ yii.

O ni ko sẹnikankan ti awọn ko le gba sinu ẹgbẹ awọn niwọn igba ti ẹni naa ba ti ṣetan lati ṣiṣẹ papọ fun ẹgbẹ onitẹsiwaju yii.

Bakan naa lo ke si gbogbo awọn agbaagba ẹgbẹ lati ṣọra fun ọrọ to ba le da wahala silẹ tabi to le fa iyapa, ti ko si le so eso rere kankan fun ẹgbẹ.

Leave a Reply