Wahala de, awọn meji di alaga PDP l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Walaha to n lọ lọwọ lẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party nipinlẹ Ekiti ko ti i dopin rara pẹlu bi ẹgbẹ naa ṣe ṣeto idibo meji ọtọọtọ lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, ti alaga meji si jawe olubori.

Bisi Kọlawọle lo di alaga ni igun gomina Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe, nigba ti Ọnarebu Kẹhinde Ọdẹbunmi di alaga fun igun Sẹnetọ Biọdun Olujimi.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, ni wahala kọkọ ṣẹlẹ nigba ti igun mejeeji ṣe idibo fawọn alaṣẹ nijọba ibilẹ. Bi igun Olujimi ṣe dibo tiwọn ni ṣekiteriati ẹgbẹ kaakiri lawọn ti Fayoṣe di tiwọn nile awọn adari ẹgbẹ.

Nibi idibo naa to waye lọjọ Satide nile itura Petim, l’Ado-Ekiti, ni Fayoṣe ati Oloye Ṣẹgun Oni toun naa jẹ gomina Ekiti tẹlẹ ti pari ija wọn, ti wọn si pinnu lati ṣiṣẹ papọ.

Lasiko naa ni Fayoṣe sọ pe PDP ti ṣetan lati gbajọba lọwọ ẹgbẹ All Progressives Congress (APC), bẹẹ ni Oni sọ pe oun yoo ṣiṣẹ takuntakun lati le APC kuro nipinlẹ naa.

Bakan naa ni Fayoṣe ki Oni kaabọ pada, o ni ile lo pada si, oun si ki i ku oriire nitori o di atunbi.

Fayoṣe kilọ fawọn ọmọ ẹgbẹ, o ni ki wọn ma huwa ọdalẹ, nitori iwa naa lo jẹ ki APC gbajọba Ekiti lọdun 2018, ṣugbọn 2020 yoo yatọ nipinlẹ naa.

O waa fọgbọn sọko ọrọ si Olujimi pẹlu bo ṣe ni ẹgbẹrun marun-un sẹnetọ ati aṣofin ko le dena de ẹni to ba ti jẹ gomina ri.

Nigba toun n sọrọ, Ọdẹbunmi ti wọn ṣeto idibo tirẹ nile itura Lotus, l’Ado-Ekiti, sọ pe atunṣe ati ayipada ti de ba ẹgbẹ PDP Ekiti bayii pẹlu bi oun ṣe di alaga.

O ni ko si ọrọ pupọ toun fẹẹ sọ lori ọrọ Fayoṣe, nitori oloṣelu naa kọ ni yoo sọ nnkan ti yoo ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ bi ko ṣe awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn pọ ju ẹni kan lọ.

O waa ni ko si awọn aṣoju ajọ eleto idibo (INEC) nibi gbogbo idibo to waye ni igun Fayoṣe, eyi to sọ igbesẹ wọn di ere ọmọde. Bakan naa lo ni ile-ẹjọ nikan ni yoo sọ igun to jẹ ojulowo, ki Fayoṣe ma ti i dunnu rara.

Leave a Reply