Wahala ẹgbẹ APC, awọn TOP ni kileeṣẹ ọlọpaa gbe kọmiṣanna to wa l’Ọṣun kuro

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn The Osun Progressives (TOP) ti wọn jẹ igun ẹgbẹ oṣelu APC ti Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla n ṣatilẹyin fun nipinlẹ Ọṣun ti ke si ọga agba patapata funleeṣẹ ọlọpaa lorileede Naijiria, IG Usman Baba, lati gbe Kọmiṣanna ọlọpaa to wa l’Ọṣun bayii, Ọlawale Ọlọkọde, kuro kiakia.

Alaga wọn, Alhaji Rasaq Ṣalinṣile, sọ fun awọn oniroyin lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, niluu Oṣogbo, pe gbogbo iwa ti Ọlọkọde n hu lori rogbodiyan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa lọwọlọwọ lo n tọka si i pe abẹ ijọba lo wa.

O ṣalaye pe kọmiṣanna naa ti gbe ojuṣe rẹ to ni i ṣe pẹlu idaabobobo ẹmi ati dukia gbogbo araalu ti sẹgbẹẹ kan, awọn ti wọn jẹ ọmọlẹyin Gomina Gboyega Oyetọla nikan lo ku ti Ọlọkọde n daabo bo.

Ṣalinṣile fi kun ọrọ rẹ pe ki nnkan too yiwọ nipinlẹ Ọṣun, Usman Baba gbọdọ gbe Ọlọkọde kuro nitori o ni ibi ti iforiti eniyan maa n de ti yoo fi pin.

A oo ranti pe nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, lawọn tọọgi kan ṣakọlu si ile Arẹgbẹṣọla, ‘Ọranmiyan House’, to wa niluu Oṣogbo, wọn yinbọn lu gilaasi ile alaja mẹrin ọhun, bẹẹ ni wọn yinbọn si ẹrọ amunawa to wa ninu ọgba naa.

Alaga TOP sọ pe to ba jẹ pe Ọlọkọde ti n gbe igbesẹ lori ikọlu ti awọn igun IleriOluwa ti n ṣe si awọn latigba yii wa, ti awọn si n fi to awọn ọlọpaa leti, iru nnkan to ṣẹlẹ l’Ọjọbọ naa ko ni i ṣẹlẹ.

O ni ipinlẹ Ọṣun ti di ibi ẹrujẹjẹ fun ẹnikẹni to ba ti ni erongba to yatọ si ti Gomina Oyetọla, ọpọlọpọ awọn ọmọ TOP ni wọn ko si le sun ninu ile ara wọn mọ latari bi awọn janduuku ṣe n dun kukulaja mọ wọn kaakiri.

O sọ siwaju pe awọn mọ lara awọn ti wọn waa ṣekọlu si Ọranmiyan House, awọn si ti fun ileeṣẹ ọlọpaa lorukọ wọn, ṣugbọn awọn ko nireti pe ohun rere kan le tibẹ jade.

Amọ ṣa, alaga ẹgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples’ Party (NNPP) nipinlẹ Ọṣun, Dokita Tosin Ọdẹyẹmi, ti ke si awọn agbaagba nipinlẹ Ọṣun lati da si wahala ojoojumọ yii.

Ninu atẹjade kan to fọwọ si, Ọdẹyẹmi sọ pe ti nnkan ba n lọ bayii, inu ewu nla ni ẹmi awọn araalu wa nitori nibi ti erin meji ba ti n ja, koriko abẹ rẹ lo maa n fori ko o.

Ọdẹyẹmi to tun jẹ akọwe agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oṣelu l’Ọṣun (IPAC), ṣalaye pe ẹgbẹ APC ti n mu kipinlẹ Ọṣun gbona nitori bi wọn ṣe n ba ara wọn ja niluu Oṣogbo ni wọn tun n ja kaakiri ijọba ibilẹ.

O ni ki ẹgbẹ naa gbejọba silẹ loṣu keje lalaafia, ki wọn ma sọ ipinlẹ Ọṣun di ibudo ogun ki wọn too kuro.

Leave a Reply