Wahala ẹgbẹ APC n le si i l’Ondo

*’Akeredolu ati alaga APC lo ni ka yọ Agboọla’

*Adajọ agba ni ko sohun to jọ ọ

*N ni alaga APC ba tun kọwe fipo silẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Lati nnkan bii ọsẹ diẹ sẹyin ni nnkan ko ti fara rọ rara nile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo pẹlu bawọn aṣofin ọhun ṣe pin si meji latari wahala to n waye laarin Gomina Rotimi Akeredolu ati Igbakeji rẹ, Ọnarebu Ajayi Agboọla.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja yii, ni gbogbo nnkan dojuru mọ awọn aṣofin mẹrindinlọgbọn naa lọwọ, ti wọn ko si ti i ri kinni ọhun yanju titi di ba a ṣe n sọ yii. Mẹrinla ninu wọn lo fọwọ siwee, ti wọn fẹẹ yọ Igbakeji gomina, Agboọla Ajayi, nipo, tawọn mẹsan-an, ninu eyi ti Igbakeji abẹnugan, olori awọn ọmọ ile to pọ ju lọ, ati olori awọn ọmọ ile to kere ju lọ kọ lati buwọ lu iwe iyọninipo ọhun.

Ko jọ ija, ko jọ ariwo, ni wọn fi pari ijokoo wọn lọjọ naa, bi wọn si ṣe n pari ipade lawọn aṣofin to n ṣatilẹyin fun igbakeji gomina ti sare kọwe si adajọ agba ipinlẹ Ondo, Abilekọ Oluwatoyin Ọlanrewaju Akeredolu, pe awọn ko lọwọ ninu igbesẹ ti awọn ẹlẹgbẹ awọn fẹẹ gbe lati yọ Ajayi nipo. Wọn fi kun un pe awọn ti hu u gbọ pe awọn ẹgbẹ awọn kan n gbero lati jawee gbele ẹ fun awọn mẹsẹẹsan-an, ki wọn le lanfaani lati mu erongba wọn sẹ.

Afi bii ẹni pe awọn aṣofin naa ti mọ ohun to fẹẹ ṣẹlẹ nitori pe asiko ti wọn tun pada jokoo lọjọ keji ti i ṣe Ọjọruu, Wẹsidee, ni wọn kede jija iwe gbele-ẹ fun mẹta ninu awọn aṣofin to ta ko iyọnipo Igbakeji gomina. Awọn mẹtẹẹta tọrọ kan ni: Ọnarebu Irọju Ogundeji to jẹ Igbakeji abẹnugan, ẹni to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Odigbo kin-in-ni, Adewale Williams Adewinlẹ, to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo keji, ati Abilekọ Favour Ṣemilore Tomomẹwọ, lati ijọba ibilẹ Ilajẹ keji.

Lati igba naa si lawuyewuye yii ti n tẹsiwaju, ti ko si ti i dawọ duro titi di asiko ta a fi n ko iroyin yii jọ lọwọ.

Wahala eyi ni wọn n wa bi wọn yoo ṣe yanju rẹ ti Alaga ẹgbẹ oṣelu APC nijọba ibilẹ Ẹsẹ Odo, Ọgbẹni Samuel Ọlọrunwa fi kọwe fipo silẹ, to si lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP pẹlu awọn alatilẹyin rẹ.

ALAROYE gbiyanju lati ba awọn aṣofin tọrọ kan sọrọ. Igbakeji abẹnugan ile, Ọnarebu Irọju Ogundeji, toun naa jẹ ọkan lara awọn ti wọn jawee gbele-ẹ fun ṣalaye pe “Ohun tawọn ẹlẹgbẹ mi ṣe lodi patapata si ohun ti ofin sọ nitori pe iwe ofin orilẹ-ede yii, tọdun 1999 ti ṣe alakalẹ igbesẹ ti wọn fi n yọ gomina tabi igbakeji rẹ nipo.

“Ko si ninu pe ka fi agbara mu eyikeyii ninu awọn aṣofin lati lọwọ ninu igbesẹ iyọninipo, o wa lori bi ọkan ẹni ọhun ba ṣe fẹ ni.

“Mi o ri idi kankan to fi yẹ ki wọn yẹ aga mọ Ọnọrebu Ajayi nidii, ohun to si ṣokunfa idi ti mi o fi ba wọn kọwọ bọwe iyọnipo rẹ niyẹn.

“Mo kilọ fun Abẹnugan ile, Ọnarebu Bamidele Ọlẹyẹlogun, pe ko ma darapọ mọ awọn eeyan lati huwa aitọ, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe ko gba si mi lẹnu.

“Loootọ lo pe mi laaarọ kutukutu ọjọ ta a kọkọ fẹẹ bẹrẹ ijokoo, to si sọ fun mi pe gomina ati alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo ti pasẹ foun lati bẹrẹ igbesẹ yiyọ Ọnarebu Ajayi kuro nipo igbakeji gomina.

“Ọnarebu Ọlẹyẹlogun gba mi nimọran lati ma ṣe yọju sile-igbmọ lọjọ naa, o ni wọn ti paṣẹ fawọn ẹṣọ alaabo pe wọn ko gbọdọ jẹ ki n wọle.

“Bo ṣe to akoko ti ipade fẹẹ bẹrẹ ni mo mori le ọna ile aṣofin, mo n reti ọlọpaa ti yoo da mi duro lati lọọ ṣe ojuṣe tawọn eeyan mi tori rẹ dibo fun mi.

“O ba mi ninu jẹ pe Abẹnugan ile pada jiṣẹ ti wọn ran an lai ri ẹsun kan gboogi ka si wa lẹsẹ, bẹẹ ni wọn ko fun wa lanfaani lati sọ tẹnu wa ki wọn too jawe gbele-ẹ fun wa.

“Ẹbẹ mi si ijọba apapọ ni pe ki wọn tete gbe igbesẹ ati gbe eto inawo gbogbo ile-igbimọ aṣofin to wa lorilẹ-ede yii kuro labẹ ijọba ipinlẹ, ki wọn si gbiyanju ati fun wọn lominira ti wọn n beere fun.

“Igbesẹ yii nikan lo le gba awọn aṣofin kuro labẹ ajaga buruku tawọn gomina n fi wọn si.

Ọrọ iyọninipo yii tun gbọna mi-in yọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja pẹlu bi Abilekọ Akeredolu to jẹ adajọ agba ipinlẹ Ondo ṣe kọ lati gba iwe iyọninipo tawọn aṣofin fi ṣọwọ si i wọle.

Ọga awọn adajọ ọhun ni awọn aṣofin naa gbọdọ tẹle ohun ti ofin sọ ko too di pe oun bẹrẹ igbesẹ lori ṣiṣagbekalẹ igbimọ ẹlẹni meje ti yoo ṣewadii ẹsun ti wọn fi kan igbakeji gomina ti wọn fẹẹ yọ nipo.

Iroyin ta a gbọ lati ijọba ibilẹ Ariwa/Iwọ-Oorun Akoko ni pe awọn agbaagba ẹgbẹ kan ti ko ara wọn jọ lati ta ko bi Ọnarebu Suleiman Jamiu Maito to jẹ olori awọn ọmọ ile to pọ ju lọ tẹlẹ ṣe kọ lati ṣatilẹyin fun Gomina Akeredolu lori igbesẹ yiyọ igbakeji rẹ nipo.

Awọn agba ẹgbẹ ọhun sọ ninu iwe kan ti wọn fọwọ si pe ki i ṣe iṣẹ ti wọn ran ọkunrin naa lo lọọ jẹ nile-igbimọ aṣofin, wọn ni iṣẹ ara rẹ lo n jẹ pẹlu bo ṣe n ṣegbe lẹyin Ajayi lasiko ti wọn fẹẹ yọ ọ nipo.

Bakan naa si lọrọ ri nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo pẹlu bawọn asaaju ẹgbẹ APC kan ṣe kọwọ bọwe pe awọn fẹẹ pe Ọnarebu Adewale Williams Adewinlẹ pada fun bo ṣe fi gomina silẹ, to n ṣatilẹyin fun igbakeji rẹ.

Ko ti i sẹni to mọ ibi ti wahala to n lọ ninu ẹgbẹ APC ipinlẹ Ondo yii yoo ja si nitori bi wọn ṣe n bọ ninu wahala kan ni wọn n ko sinu omi-in.

Leave a Reply