Wahala ẹgbẹ onimọto l’Ekoo: Eyi nidii tijọba fi fofin de NURTW lẹyin ti MC loun ko ba wọn ṣe mọ

Faith Adebọla

Latari awuyewuye to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ onimọto, National Union of Road Transport Workers (NURTW), ẹka ti ipinlẹ Eko, ijọba ti fofin de ẹgbẹ naa, wọn ni wọn o gbọdọ ṣiṣẹ agbero, tabi ja tikẹẹti, wọn o si gbọdọ gbowo lọwọ awọn onimọto kaakiri gbogbo ibudokọ ati gareeji nipinlẹ Eko.

Ifofinde yii waye lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna feto iroyin ati ọgbọn-inu nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Gbenga Ọmọtọṣọ, fi lede, o ni ijọba gbe igbesẹ yii lati daabo bo awọn ero ati araalu, ati ki wọn le dena ija to ṣee ṣe ko bẹ silẹ.

Atẹjade naa ka lapa kan pe:

“Ijọba ipinlẹ Eko ti n woye ohun to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ NURTW, bi awuyewuye ṣe dide lori ipo alaga ẹgbẹ naa, ti itakora si n ṣẹlẹ lọtun-un losi.

“Ojuṣe ijọba ni lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn onile ati alejo niluu Eko, tori naa, o pọn dandan ka tete bomi pana awuyewuye to dide naa, ka le daabo bo araalu lọwọ ewu to le ṣẹlẹ bi ọrọ yii ba lọọ dija.

“Lẹyin ta a wo ohun ti ofin sọ, ijọba pinnu lati fofin de ẹgbẹ onimọto NURTW ati igbokegbodo wọn. Wọn o gbọdọ ṣiṣẹ ni gbogbo gareeji ati ibudokọ ero nipinlẹ Eko. Ijọba maa gbe igbimọ kan dide lati bẹrẹ si i ṣakoso awọn gareeji ati ibudokọ wọnyi laipẹ, awọn alẹnulọrọ lẹka eto irinna maa wa lara igbimọ yii.”

Ṣaaju asiko yii lawọn agbofinro ti lọọ duro wamuwamu pẹlu nnkan ija si ọfiisi ẹgbẹ naa to wa l’Opopona Ọladoje, lagbegbe Oko-Ọba, l’Agege, bẹẹ ni wọn si wa lawọn gareeji ati ibudokọ ero pataki bii Oṣodi, Iyana-Ipaja, Abule Ẹgba, Ketu, ati Ọbalende, ati awọn mi-in, ọkọ wọn si n patiroolu kiri.

Ṣe l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹta yii, ni igbimọ alakooso apapọ ẹgbẹ naa jawee gbele-ẹ fun Alaga NURTW l’Ekoo, Ọgbẹni Musiliu Ayinde Akinsanya, tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ, wọn yọ ọ nipo alaga, wọn ni ko lọọ rọọkun nile na, titi di ọjọ mi-in ọjọ ire.

Ninu lẹta ti wọn fi kede iyọnipo rẹ, eyi ti Alaaji Kabiru Ado Yau buwọ lu lorukọ igbimọ alakooso apapọ, wọn fẹsun kan MC Oluọmọ pe o tapa sofin ẹgbẹ, o huwa ta-ni-maa-mu-mi, o ri awọn agbaagba apapọ ẹgbẹ fin, o si n da rogbodiyan silẹ laarin ẹgbẹ onimọto Eko, latari bo ṣe kọ lati tẹle aṣẹ ti igbimọ alakooso apapọ pa fun ọ lolu-ile ẹgbẹ l’Abuja, lọjọsi.

Wọn tun fẹsun kan ọkunrin naa pe o fi igbimọ apapọ gun lagidi lori iwe waa-wi-tẹnu-rẹ ti wọn fi ṣọwọ si i lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ati lọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun yii, pẹlu bo ṣe kọ lati fesi pada. Tori ẹ, wọn ni ko ko gbogbo dukia ẹgbẹ to ba wa nikaawọ rẹ fun igbakeji rẹ ati akọwe.

Ṣugbọn bi lẹta wọn ṣe n tẹ MC Oluọmọ lọwọ loun naa fesi. Oun ati awọn ẹmẹwa rẹ kan pe ipade awọn oniroyin, wọn si kede pe awọn ti ya kuro lara ẹgbẹ apapọ NURTW, wọn lawọn o ṣẹgbẹ naa mọ.

Nibi ipade kan ti wọn ṣe nile ẹgbẹ wọn to wa l’Agege, nipinlẹ Eko, ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni wọn ti kede pe Akinsanya ati gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto NURTW ti kuro ninu ẹgbẹ apapọ onimọto yii. Wọn ni gbogbo ọna ti awọn gba lati jẹ ki alaafia jọba, kawọn si yanju ede-aiyede to n lọ laarin awọn atawọn adari ẹgbẹ naa lo ja si pabo.

Wọn fi kun un pe awọn ọmọ ẹgbẹ awọn paapaa ṣewọde ifẹhonu han lọ si ọdọ Gomina Babajide Sanwoolu.

Nitori pe awọn si jẹ ẹni to bọwọ fofin, ti ko ni i fẹ ki wahala kankan ṣẹlẹ, tabi ki ohunkohun da alaafia ipinlẹ Eko ti awọn fẹran daadaa ru loun gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ naa ati gbogbo oloye ẹgbẹ yooku atawọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn wa ni ẹka to to bii igba (200) kaakiri ipinlẹ Eko pe awọn ti kuro ninu ẹgbẹ NURTW, awọn ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ naa mọ.

O ni igbesẹ ti awọn gbe yii wa ni ibamu pẹlu ofin ilẹ wa to fi aaye gba ẹnikẹni lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu tabi ẹgbẹ mi-in to ba wu u lai ṣe pe ẹnikẹni halẹ mọ ọn tabi fiya jẹ ẹ.

Bẹẹ lo lawọn ti ṣetan lati fi ipinnu awọn han si Gomina Babajide Sanwoolu, ileeṣẹ to n ri si igbokegbodo ọkọ l’Ekoo ati gbogbo ẹka yooku to ba yẹ.

Akinsanya waa rọ ijọba ipinlẹ Eko lati gba isakoso idari ọkọ nipinlẹ Eko nipa ṣiṣe idasilẹ igbimọ ti yoo maa mojuto awọn onimọto ati garaaji kaakiri to pe ni Park Management Committee, titi ti ọrọ naa yoo fi yanju, ti alaafia yoo si jọba.

O waa gba awọn ọmọ ẹgbẹ naa nimọran pe ki wọn maa ṣiṣẹ wọn lọ lai sewu, ti wọn ba si ri awọn ọlọpaa lawọn gareeji wọn, ki wọn ma bẹru, wọn wa nibẹ lati daabo bo wọn ni.

Lẹnu ọjọ mẹta yii lawọn kan ti n gbe e kiri pe MC Oluọmọ atawọn ẹgbẹ rẹ kan fẹẹ ya kuro ninu ẹgbẹ onimọto apapọ, ti wọn si fẹẹ lọọ da ẹgbẹ mi-in silẹ.

Asiko naa lawọn oloye ẹgbẹ kan pariwo pe wọn n fi tipa mu awọn lati sọ pe awọn ko ṣe NURTW mọ, ati pe ẹgbẹ tuntun yii lawọn fẹẹ maa ṣe.

Ko pẹ sigba naa ni wọn fun MC ni iwe pe ko waa sọ tẹnu rẹ, lẹyin rẹ ni wọn si rọ ọ loye alaga fun igba ti ẹnikẹni ko le sọ.

Awọn kan ti n sọ pe ọrọ ija to n lọ naa lọwọ kan oṣelu ninu. Ko si ti i sẹni to mọ ibi ti ọrọ naa yoo ja si.

 

 

Leave a Reply