Wahala Ire-Ekiti: Awọn ọlọpaa ni ki i ṣe ọta ibọn awọn lo pa awọn to ku

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti kede pe ọta ibọn kọ lo pa awọn meji to padanu ẹmi wọn nibi rogbodiyan to waye niluu Ire-Ekiti, nijọba ibilẹ Ikọle, lanaa ọjọ Aje.

Alukoro ileeṣẹ naa, ASP Sunday Abutu, ṣalaye lonii pe awọn to n fi kumọ ati nnkan ija oloro mi-in ja lo pa awọn eeyan naa, ki i ṣe ọta ibọn ọlọpaa rara.

Lọjọ Aiku, Sannde, ijẹta, ni wahala bẹ silẹ niluu naa lẹyin ti Onire, Ọba Victor Bọbade, kede pe ko si ọdun Ogun lọdun yii, latari aṣẹ ijọba lati dena arun Korona.

Eyi lo bi awọn kan ninu ti wọn fi da wahala silẹ, ọrọ naa si di nnkan nla lanaa, nibi ti eeyan meji ti pada gbẹmiin mi, ti wọn si ba ọpọlọpọ dukia jẹ.

Ni bayii, awọn ọlọpaa ti mu eeyan kan ti wọn sọ pe oun lo dari awọn to paayan, wọn si ni awọn n wa awọn to le ni mẹẹẹdogun di asiko yii.

Leave a Reply