Wahala l’Ado-Ekiti, ibọn ba ọlọpaa lasiko rogbodiyan, wọn lawọn ẹgbẹ ẹ lo yinbọn pa a

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Iwadii ti berẹ lori iku ọlọpaa adigboluja kan ti wọn yinbọn pa lasiko rogbodiyan to waye ni teṣan ọlọpaa agbegbe Okeṣa, l’Ado-Ekiti, lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.

Ọlọpaa ọhun nibọn ba lẹsẹ nigba tawọn eeyan kan kọ lu teṣan naa nitori ọrọ to jẹ yọ lori iku ọlọkada kan ti mọto pa.

Ẹnikan to mọ nipa ọrọ naa sọ fun ALAROYE pe onimọto kan lo pa ọkunrin kan to wa lori ọkada, ẹya kan nipinlẹ Benue lọkunrin ọhun si ti wa. Loju-ẹsẹ lawọn eeyan to wa nibẹ ti mu awakọ ọhun, wọn si fa a le ọlọpaa lọwọ, bẹẹ ni wọn gbe e lọ si teṣan agbegbe ti wọn n pe ni Area Command ọhun.

Iṣẹlẹ yii lo ni o gbe awọn eeyan oloogbe wa si teṣan, nibi ti wọn ti sọrọ pẹlu onimọto naa, ti wọn si ni ko fun awọn ni ẹgbẹrun lọna irinwo-le-aadọrin naira (N470,000), nitori awọn ko ba a ṣẹjọ, owo naa lawọn yoo si fi ṣeto isinku oloogbe nigba tawọn ba gbe e pada siluu awọn.

Owo yii la gbọ pe o da wahala silẹ pẹlu bawọn eeyan naa ṣe sọ pe awọn ọlọpaa fẹẹ yọ ninu ẹ, ati pe wọn ko fẹẹ gbe oku oloogbe fawọn. Eyi lo jẹ ki wọn ya bo teṣan ọlọpaa ọhun, wọn si ko oriṣiiriiṣii nnkan ija bii okuta ati igi dani.

Iro ibọn lawọn eeyan fi mọ pe wahala ti ṣẹlẹ, ibẹrubojo si ba awọn eeyan to wa lagbegbe ọhun, paapaa awọn ontaja, ni kaluku ba sare ti ṣọọbu ẹ ki wọn too fẹsẹ fẹ ẹ.

Awọn ọlọpaa le awọn eeyan ọhun jade loootọ nigba ti wọn yinbọn, lasiko naa ni ibọn si ba ọlọpaa adigboluja kan lẹsẹ, eyi lo pada gbẹmi ẹ lọjọ naa.

A gbọ pe awọn ọlọpaa mu awọn kan ninu awọn to ṣakọlu yii, ṣugbọn awọn to ku ko kuro lagbegbe ọhun fun ọpọlọpọ iṣẹju.

Nigba to n ba akọroyin wa sọrọ lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, ASP Sunday Abutu to jẹ Alukoro ọlọpaa Ekiti sọ pe loootọ niṣẹlẹ naa waye, ṣugbọn iwadii n lọ lati mọ ẹni to yinbọn pa ọlọpaa naa gan-an.

Abutu ni, ‘‘Loootọ lawọn ọlọpaa gba mọlẹbi ẹni ti mọto pa ati dẹrẹba yẹn laaye lati jọ sọrọ, o si gba lati san ẹgbẹrun lọna ojileninirinwo naira (N440,000), eyi ti mọlẹbi oloogbe gba.

‘’Ṣugbọn ninu owo yẹn, o yẹ ki ẹni to ni ọkada gba ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira (N150,000), iyẹn lawọn mọlẹbi gbọ ti wọn fi ni awọn ọlọpaa fẹẹ lu awọn ni jibiti. Di bi a ṣe n sọrọ yii, wọn ko ti i fun ẹni naa lowo ẹ.

‘’Nibi ti wọn ti n pariwo pẹlu awọn nnkan ija oloro pe ki wọn fa onimọto yẹn le awọn lọwọ kawọn da sẹria fun un lawọn ọlọpaa ti yin tajutaju, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe ibọn bẹrẹ si i dun kaakiri agbegbe naa, eyi to ba ọlọpaa to pada ku yii.’’

O waa ni ko si ootọ ninu pe awọn ọlọpaa lo yinbọn pa eeyan wọn ọhun nitori iwadii ko ti i fidi ẹ mulẹ, awọn yoo si ri i pe ododo to wa ninu ọrọ naa jẹyọ laipẹ.

Leave a Reply