Wahala mi-in tun n bọ laarin ASUU ati ijọba apapọ 

Awọn oloye ẹgbẹ olukọ Yunifasiti, iyẹn ASUU, ti sọ pe awọn ṣi n duro de owo ajẹmọnu ogoji biliọnu naira ti ijọba apapọ ṣeleri lẹyin ọjọ kejila ti awọn ti fagi le iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ ti wọn gun le tẹlẹ.

Yatọ si eyi, wọn ni ijọba tun ti kuna lati sanwo oṣu fawọn olukọ ti orukọ wọn ko ti i wọnu ẹrọ igbalode to n ṣamojuto bi owo ṣe n wọle sinu apo ifowopamọ awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ, lẹyin owo oṣu meji ti wọn ti gba ninu oṣu kejila, ọdun to kọja.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila, ọdun 2020, ni awọn ASUU fagi le iyanṣelodi wọn lẹyin asọyepọ to waye laarin awọn oloye ẹgbẹ naa ati minisita fun ọrọ awọn oṣiṣẹ ati eto igbanisiṣẹ, Dokita Chris Ngige, lọjọ kejilelogun, oṣu kejila, ọdun to kọja.

Lasiko naa ni ijọba apapọ san owo-oṣu meji ninu mẹfa ti wọn gbẹsẹ le, to si ku oṣu mẹrin tijọba n jẹ wọn.

Lara ohun ti wọn jọ fẹnuko le lori ni pe ijọba apapọ yoo san ogoji biliọnu naira ti i ṣe owo ajẹmọnu laarin igba naa si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2020.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba apapọ ti ṣeleri lati sanwo oṣu ti wọn jẹ wọn lẹyin ti Dokita Chris Ngige ti gbaṣẹ lọwọ Aarẹ Buhari pe ki wọn bẹrẹ si i fun wọn lowo oṣu wọn, sibẹ ẹgbẹ ASUU sọ pe o ti digba meji ọtọọtọ bayii ti ijọba yoo kuna lati mu ileri ẹ ṣẹ.

Wọn ni ijọba apapọ ko ti i san  ogoji biliọnu naira to ṣeleri, bakan naa ni ko ti i san owo-oṣu mẹrin to ti jẹ silẹ bayii, gẹgẹ bo ṣe ṣeleri ẹ nibi ipade ti wọn ṣe lọjọ kejilelogun, oṣu kejila, ọdun to k̀ọja.

Ohun to ṣẹlẹ yii lo mu awọn eeyan kan maa sọ pe o ṣee ṣe ki wahala mi-in tun bẹ silẹ laarin wọn lẹyin iyanṣẹlodi oṣu mẹsan-an ti wọn ṣẹṣẹ yanju ẹ yii ti ijọba apapọ ko ba tete gbe igbesẹ lori ibeere awọn ASUU.

 

Leave a Reply