Wahala n bọ o: Awọn tanka epo ko ni i wọ Eko lati Mọnde

Oluyinka Soyemi

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe awọn tanka to n gbe epo bẹntiroolu ko ni i wọ Eko lati ọjọ Aje, Mọnde, ọtunla, ti ijọba ipinlẹ naa ko ba gbe igbesẹ.

Eyi ni aṣẹ ti Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ bẹntiroolu ati gaasi nilẹ yii (NUPENG) pa fawọn awakọ tanka epo lẹyin ti wọn ni ijọba ko da si nnkan to n dun awọn.

Ninu atẹjade kan ti William Akporeha to jẹ alaga ẹgbẹ naa nilẹ yii ati Ọlawale Afọlabi to jẹ akọwe agba fọwọ si, aago mejila oru ọjọ Aje, Mọnde, ni iyanṣẹlodi naa yoo bẹrẹ.

Wọn ni awọn ti ke si ijọba Eko ati ikọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari gbe kalẹ lati ṣiṣẹ lori ibudo Apapa, awọn si tun ni ki wọn gba awọn lọwọ awọn agbofinro ati ọmọọta to n gba owo ribiribi lọwọ awọn, ṣugbọn ko jọ bii ẹni pe ọrọ naa ka ijọba lara.

Leave a Reply