Wahala n bọ:Awọn ọtẹlẹmuyẹ pagbo yi ofiisi olori banki apapọ ilẹ wa ka

Ọrẹoluwa Adedeji

Asiko yii ki i ṣe eyi to dara fun olori banki apapọ ilẹ wa Central Bank of Nigeria (CBN), Godwin Emefiele, pẹlu bi awọn ọlọpaa ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ṣe kora wọn jọ digbọn digbọn yi ọfiisi ọkunrin naa ka lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii, ti wọn si n dọdẹ rẹ bii igba ti ọdẹ ba n dọdẹ ẹranko ninu igbo.

Nibi ti awọn agbofinro naa pọ de, mọto bii ogun ni wọn gbe wa, ti wọn si dira bii ẹni to n lọ si oju ogun.

Nibi to le de, wọn ko gba oṣiṣẹ ileeṣẹ banki apapọ ilẹ wa yii kankan laaye ko sun mọ ẹnu ọna ọfiisi ọga agba yii, bẹẹ ni ọkunrin naa ko si nibi iṣẹ, bo tilẹ jẹ pe o ti de lati ilu oyinbo to lọ laipẹ yii.

Tẹ o ba gbagbe, wahala kan ti wa laarin Emefiele atawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ yii lori ẹsun ti wọn fi kan an nigba kan pe o n ṣonigbọwọ fun awọn afẹmiṣofo.

Awọn ọtẹlẹmuyẹ si lọ sile-ẹjọ nigba naa lati gba aṣẹ ki wọn le mu un, ṣugbọn ile-ẹjọ ko gba ẹbẹ wọn wọle, wọn si fofin de awọn ọtẹlẹmuyẹ naa pe wọn ko le mu un, bẹẹ ni wọn ko le pe e lati waa sọ ohunkohun tabi ki wọn ti i mọle.

Lasiko ti ọrọ atunto owo banki ilẹ wa di wahala pẹlu ote ti ọkunrin naa fi le iye ti ẹni kọọkan le maa gba lojumọ ninu asunwọn rẹ ni wahala naa bẹrẹ, awọn aṣofin ranṣẹ pe e lori ọrọ yii, ṣugbọn ko jẹ ipe wọn.

Latigba naa ni ẹsun oriṣiiriṣii ti bẹrẹ si i jade nipa ọkunrin toun naa kọkọ loun fẹẹ du ipo aarẹ Naijiria ko too di pe o jawọ yii. Lara ẹsun tawọn kan si ka si i leṣẹ naa ni pe o n ṣe onigbọwọ fun awọn afẹmiṣofo.

Ninu wahala naa lo ti lọ si oke okun, o ni oun n lọọ lo isinmi oun lẹnu iṣẹ lọhun-un, eyi to yẹ ko pari ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii.

O jọ pe ni imurasilẹ lati pada sẹnu iṣẹ lo mu ki ọkunrin naa pada de lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlogun. Ṣugbọn lọjọ to de yii gan-an ni awọn ọtẹlẹmuyẹ lọọ tẹlẹ de e ni ọọfiisi rẹ. Nibi ti nnkan si de duro, ko si tabi ṣugbọn kan nibẹ, bi ọkunrin naa ba yọju si ọfiisi lọjọ Iṣẹgun, afaimọ ki wọn ma gbe e janto.

Adajọ ni ki wọn yẹgi fun Rafiu atawọn ọrẹ ẹ to dana sun Victor lẹyin ti wọn gbowo ọwọ ẹ l’Ọṣun

Leave a Reply