Wahala ni Muṣin, ọlọpaa atawọn ọmọọta koju ija sira wọn

Kazeem Ọlajidè

Wahala buruku ni ALAROYE gbọ pe o n ṣẹlẹ lọwọ bayii niluu Muṣin, nipinlẹ Eko laarin awọn ọdọ kan to n ṣewọde atawọn ọlọpaa.

Niṣe lọrọ di bo o lọ o yago ni nnkan bii aago kan aabọ ọsan ọjọ Isegun, Tusidee, ọsẹ yii, nigba ti ija bẹ silẹ, eyi ti a ko ti i mọ ohun to fa a gan an.

Bi awọn to n ta ọja ṣe n sare palẹmọ, bẹẹ lawọn mi-in naa n wa ibi fori pamọ si, nitori ibọn atawọn ohun ija oloro mi-in ti awọn to n fa wahala yii n lo nibi iṣẹlẹ naa.

Ẹni kan to ba akọroyin wa sọrọ sọ pe ẹmi eeyan paapaa ti bọ ninu wahala ọhun, ṣugbọn oun ko le sọ pato iye awọn ti wọn ti ba iṣẹlẹ yii lọ.

Tẹ o ba gbagbe, bii teṣan ọlọpaa meji ni wọn ti dana sun lawọn ibi kan nipinlẹ Eko lọjọ Iṣẹgun, bẹẹ ni Gomina Babajide Sanwo-Olu naa ti paṣẹ pe konilegbele kaakiri ipinlẹ Eko pẹlu bi wahala ọhun ṣe n fẹju si i.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Pasitọ Chibuzor fun awọn obi Deborah ni ile fulaati mẹrinla atawọn ẹbun mi-in

Monisọla Saka O da bii pe iku Deborah, ọmọbinrin ti awọn awọn kan juko pa, …

Leave a Reply

//zikroarg.com/4/4998019
%d bloggers like this: