Wahala n’Ikire: Awọn janduku kọlu Ọba Akire, wọn tun ja awọn oloye ẹ lole rẹpẹtẹ

Aderounmu Kazeem

Paroparo niluu Ikire, nipinlẹ Ọṣun, da bayii pẹlu bi awọn janduku ṣe bẹrẹ wahala lati ana ọjọ Aiku, Sannde, ti wọn si tun n fa a lọ lọwọlọwọ.

Gbogbo mọto to n bọ lati Ibadan, atawọn to n bọ lati Oṣogbo, Ile-Ifẹ, ti wọn ko le maa gba ilu ọhun kọja ni ọna ti di mọ bayii, ti awọn ṣọja si ti gba igboro kan pẹlu awọn ẹṣọ agbofinro mi-in.

ALAROYE gbọ pe, adugbo kan ti wọn pe ni Sango ni wahala ti kọkọ bẹrẹ laṣalẹ ana, nigba ti yoo si fi di owurọ oni, kinni naa ti burẹkẹ, o si ti di wahala nla laarin ilu.

Ni deede aago mẹjo aarọ ni wọn sọ pe awọn janduku ọmọọta ti ko pankẹrẹ lọwọ niwaju teṣan ọlọpaa ilu naa.

Wọn ni ki oloju too ṣẹ ẹ, niṣe lawọn janduku naa ya wọ aafin Ọba Akire, Ọba Ọlatunde Falabi, lasiko to n ṣepade pẹlu awọn oloye.

Iya buruku ni wọn sọ pe wọn fi jẹ Ọba alaye naa pẹlu awọn oloye rẹ.

Wọn ni bi wọn ṣe gba foonu wọn, bẹẹ ni wọn gba kaadi ATM ti wọn fi n gbowo, ti kaluku si ba ere buruku kuro laafin ọba pada sile wọn.

Lara awọn oloye, ti wọn gba owo lọwọ ẹ ati foonu ni Ẹkẹrin ilu Ikire, Oloye Ọlalekan Saheed Akinrẹmi.

Lẹyin ti wọn ti ja wọn lole tan laafin, niṣe lawọn eeyan yii ya siluu, ti wọn n da ilu ru gidigidi.

Lojuẹsẹ naa lawọn ṣọja ti de, ti wọn n yinbọn, tawọn janduku yii naa n yinbọn lu wọn pada.

Ohun ta a tun gbọ ni pe, ṣaaju asiko yii lawọn janduku ti n wa gbogbo ọna lati dana sun teṣan ọlọpaa to wa niluu Ikire, ṣugbọn ti alaga ijọba ibilẹ naa, Ọmọọba Aderẹmi Abass rọ wọn gidigidi, ki wahala ọhun too tun gbọna mi-in yọ loni-in.

Ju gbogbo ẹ lọ, oloko ko le lọ soko niluu Ikire, bẹẹ ni olodo paapaa ko le re ibi kan, niṣe ni kaluku ti ilẹkun mọri gbagba, ti awọn eeyan si n sa fun aṣịta ibọn ẹṣọ l̀ọwọ awọn agbofinro tabi tawọn janduku to gba igboro kan.

Leave a Reply