Wahala ninu ijọ Sinagogue, iyawo TB Joshua fi EFCC mu awọn adari ijọ kan

Faith Adebọla, Eko

Yoruba bọ, wọn ni b’ọgẹdẹ ba ku, aa fọmọ rẹ rọpo, bi aladi ko si nile, ọmọ rẹ aa jogun ẹbu, ṣugbọn ọrọ ko gba bẹẹ mọ bayii ni ṣọọṣi Synagogue, ileejọsin gbajugbaja Ajihinrere agbaye nni, Oloogbe Temitọpẹ Balogun Joṣhua, latari bawọn eeyan kan nileejọsin naa ṣe lawọn o ni i gba ki Evelyn Joshua bọ sipo adari ijọ SCOAN ọhun.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn kan ti wọn wa ninu ẹgbẹ GCSM, Global Congress of SCOAN Members ṣe sọ ninu atẹjade kan ti wọn fi lede fawọn oniroyin niluu Akurẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, pe ilana ti wọn fi yan iyawo oludasilẹ ileejọsin naa, Evelyn, gẹgẹ bii adari ijọ naa ko bofin mu rara, wọn ni adabọwọ ati ọgbọn arumọje ni wọn fẹẹ fi gbe obinrin naa sipo aṣaaju.

Atẹjade naa, eyi ti Aarẹ ẹgbẹ GCSM, Ọpẹyẹmi Adedeji, ati Akọwe wọn, Chimezie Brown, buwọ lu, sọ pe niṣe lawọn kan mọ-ọn-mọ fẹẹ tẹ ilana ati ofin mọlẹ, ko le ṣee ṣe fun obinrin yii lati ki ẹsẹ si bata oludari, ti ọkọ rẹ bọ silẹ ọhun.

Wọn ni ero ati ilana ti Oludari SCOAN, Synagogue Church of All Nations, Oloogbe TB Joshua, fi lelẹ ni pe ki oludari to maa tẹle oun jẹ ọkan lara pasitọ ṣọọṣi naa to ti fororo yan ko too ku.

Wọn ṣalaye pe loootọ ni Evelyn Joshua jẹ iyawo oloogbe, ṣugbọn ko si lara awọn pasitọ ileejọsin ọhun, bẹẹ ni wọn o fororo yan an nigba kankan sẹyin.

Atẹjade ọhun kegbajare si gbogbo awọn olujọsin SCOAN lati ma ṣe woran ohun to n lọ lasiko yii, wọn lawọn o fẹ kileejọsin naa parun tabi ki ala ati ireti oludasilẹ wọn ja sofo lẹyin iku rẹ.

Ṣugbọn awọn kan ta ko erongba yii, wọn ni oloogbe naa ko fi ilana pato kan silẹ lati yan ẹni ti yoo bọ sipo to ba ku, tori ọkunrin naa ko tilẹ ni in lero pe iku to yawọ bẹẹ le pa a lojude lai ro ti lọjọ karun-un, oṣu kẹfa, ọdun yii, to doloogbe. Wọn ni ipinnu ti igbimọ adari ijọ ṣe lati fa ipo naa le iyawo rẹ lọwọ dara gidi, tori ẹnikan to sun mọ ọkọ rẹ pẹkipẹki ju lọ lobinrin naa.

Ṣe latigba ti TB Joshua ti ku, ti wọn si ti sinku rẹ, ni nnkan bii oṣu mẹta sẹyin ni awuyewuye ti dide nipa ẹni ti yoo bo sipo oludari to ṣofo ọhun.

Ki ọwọ iyawo oloogbe yii le tẹ ohun to n wa ọhun, obinrin naa lọ sile-ẹjọ pẹlu ẹbẹ pe ki wọn kede oun gẹgẹ bii ọkan lara awọn ọmọ igbimọ aṣeegbọkanle, iyẹn Board of Trustee, ti ṣọọṣi SCOAN naa.

Adajọ Tijani Ringim tile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko kan dajọ lọsẹ to kọja pe loootọ ni, memba igbimọ naa lobinrin yii i ṣe, o si lẹtọọ si gbogbo ipo ati anfaani to ba ṣi silẹ nileejọsin ọhun.

Ọjọ meji lẹyin eyi ni igbimọ naa lawọn ti yan obinrin yii lati maa tukọ ijọ naa niṣo, latibi ti ọkọ rẹ pari iṣẹ si, bo tilẹ jẹ pe ipinnu naa ko dun mọ awọn kan ninu.

A gbọ pe ṣaaju asiko yii ni obinrin yii ti n paṣẹ lori awọn oloye ṣọọṣi ọhun, paapaa awọn to ba fura pe wọn o nifẹẹ si boun ṣe fẹẹ bọ sipo oludari ijọ naa, wọn lo gba yara tawọn kan n gbe ninu agbala ileejọsin ọhun to wa niluu Ikọtun-Egbe, nipinlẹ Eko, lọwọ wọn, bẹẹ lo gba ẹrọ alagbeekan ti wọn fun awọn kan lara wọn, o si fofin de awọn mi-in lara wọn pẹlu.

Ohun mi-in ta a tun gbọ ni pe obinrin naa fẹsun kan awọn kan lara awọn oloye ijọ ọhun pe ole ni wọn, onijibiti si ni wọn pẹlu, o ni gbara ti ọkọ oun ti ku ni wọn ti bẹrẹ si i gbe awọn owo ijọ atawọn dukia kan gba ẹyin, ti wọn si ti n da akọsilẹ ati iṣiro ṣọọṣi naa ru.

Lati fidi eyi mulẹ, wọn ni iwe kan ti lọ sọdọ ajọ to gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣẹ owo mọkumọku nni, EFCC (Economic and Financial Crimes Commission) lati ba wọn yẹ iwe owo ṣọọṣi naa wo finni-finni, ki wọn si gbe igbesẹ lori awọn aleebu ti wọn ba ri.

Leave a Reply