Wahala nla bẹ silẹ nibi Ọdun Ijẹsu nipinlẹ l’Ondo

 

 Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Lara ọjọ kan ti ko ni i ṣe e gbagbe bọrọ lọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 yii, jẹ fawọn ara ilu Ibulẹṣọrọ, eyi to wa nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, nipinlẹ Ondo, nitori ohun tawọn eeyan ko rokan rẹ rara lo waye lasiko ayẹyẹ ọdun ijẹsu ti wọn ṣe niluu ọhun lọjọ yii.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ nipa iṣẹlẹ ọhun pe awọn ọlọpaa ati ṣọja kan ni  wọn lọọ ya bo wọn ninu ilu ọhun lasiko ti wọn n ṣe ayẹyẹ ọdun ijẹsu to maa n waye lọdọọdun, ti wọn si n yinbọn soke kikankikan, bẹẹ ni wọn tun n fi ibọn tajutaju ṣọkọ fun awọn ti wọn ba fẹẹ ṣe agidi diẹ ninu awọn ọlọdun naa.

Ọkan ninu awọn araalu ọhun to bawọn oniroyin sọrọ laṣiiri ni, ko si ani- ani pe Oníbulẹ̀ tuntun, iyẹn Ọba Leke Ogunlade, lo dẹ awọn ẹṣọ alaabo naa si awọn eeyan, nitori awọn mọ pe gbogbo ọna lo n wa ki ọdun naa ma baa ṣee ṣe.

O ni lojiji ni awọn n gbọ iro ibọn kíkankíkan nibi ti awọn ti n ba eto ayẹyẹ ọdun ijẹsu lọ, ko si pẹ rara to ni awọn ri ọlọpaa atawọn ṣọja ti wọn ya de, ti wọn si n doju ibọn tajutaju kọ ẹnikẹni ti wọn ba ti ri.

Ọpọ ile lo ni wọn ja wọ lati fi pampẹ ofin gbe awọn eeyan lẹyin ọpọlọpọ wakati ti wọn ti kọkọ fi ṣoro bii agbọn laarin igboro, ninu eyi tọpọ awọn eeyan ti fara pa yanna yanna, ti wọn si wa lọsibitu ti wọn ti n gba itọju lọwọ.

Ọkunrin to ni ka f’orukọ bo oun laṣiiri ọhun ni ko ti i ye awọn rara ọjọ ti ọdun ijẹsu ṣiṣe tun pada di ohun to lodi labẹ ofin, tawọn ọlọpaa fi wa n tori rẹ doju ija kọ awọn ẹni ẹlẹni.

O ni o ti lọjọ tawọn maa n ya sọtọ lọdọọdun fun ayẹyẹ ọdun ibilẹ naa, ṣugbọn ti Ọba Ogunlade fẹẹ yi i pada nitori imọtara rẹ nikan.

O ni ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, lo fẹẹ mọ-ọn-mọ gbe ọdun naa si lati fi ṣe ami ayẹyẹ ọjọ to gba ọpa aṣẹ. Igbesẹ yii lo ni ko dun mọ awọn araalu ninu rara, ti wọn si n beere pe bawo ni ẹnikan yoo ṣe dori aṣa kodo, ti yoo yi ọjọ ti awọn ti n ṣọdun iṣẹnbaye awọn pada nitori ti ara rẹ nikan?

Lara ohun to lo ṣokunfa ede aiyede to n waye laarin awọn araalu ati ọba to ṣẹṣẹ joye ọhun ree, ki ọrọ ọhun too waa pada burẹkẹ si i lọjọ to yẹ kí wọn ṣe ọdun naa.

Wahala mi-in to tun wa laarin awọn eeyan ilu Ibulẹṣọrọ ati Ọba Ogunlade ni ọna ti wọn lawọn afọbajẹ fi yan an gẹgẹ bii Oníbulẹ̀, eyi ti ko fi bẹẹ dun mọ awọn kan ninu.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni ọjọ pẹ loootọ ti wahala ti wa lori ọrọ oye niluu Ibulẹṣọrọ.

O ni awọn ti figba kan ranṣẹ si gbogbo awọn ti ọrọ kan lati ba wọn yanju rẹ nitubi inubi, ti awọn si jẹ ko ye awọn tinu ba n bi lati fẹsẹ ofin tọ ọrọ naa.

Ọdunlami ni kete ti awọn gbọ pe ija nla ti bẹ silẹ laarin awọn araalu ọhun lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu yii, ni awọn ti sare lọ sibẹ lati tete pana rẹ ko too d’ohun ti apa ko ni i fẹẹ ka mọ.

 

Leave a Reply