Wahala nla ni yoo da silẹ ti wọn ba pa ẹnikẹni ninu awọn ọdọ to n ṣe iwọde yii- Oyedepo

Aderohunmu Kazeem

“Lọdun 2015, ni mo ti ri i wi pe ewu nla kan n bọ, bẹẹ ni mo sọ ọ, ṣugbọn wọn ko gbọ, ni bayii tawọn ọdọ ti yari, afi ki a ṣe pẹlẹ, ki ọrọ naa ma le ju ohun ti apa ko ni i ka mọ.”

Bi Bisọọbu David Oyedepo ti ijọ Winners, ṣe bẹrẹ iwaasu ẹ lori ifẹhonu han awọn ọdọ to n ṣẹlẹ kaakiri orilẹ-ede Naijiria niyi lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni ṣọọṣi ẹ to wa ni agbegbe Iyẹsi, niluu Ọta, ipinlẹ Ogun.

Ojiṣẹ Ọlọrun yii sọ pe loootọ ni awọn ọdọ lẹtọọ lati beere fun ẹtọ wọn, ati pe oun mọ-ọn-mọ dakẹ lai sọ ohunkohun lati bii ọjọ meloo kan sẹyin ti iwọde ọhun ti bẹrẹ ni.

O ni, “Mo ti ri i pe ewu nla n bọ, bẹẹ ni mo kilọ titi, sugbọn wọn kọ, wọn ko ka a kun. Ti a ba wo orilẹ-ede yii lati nnkan bii ọdun marun-un sẹyin, a oo ri i pe idaamu ko ba awọn ọmọ Naijiria to bayii ri, ipakupa atawọn iṣẹlẹ aburu mi-in lo gbode kan. Ti ọrọ ba si ri bẹẹ, ko si ki ifẹhonu ma waye, paapaa latọwọ awọn ọdọ, nitori wọn ko mọ ẹni tọrọ ọhun tun le kan to ba ya. Iyẹn gan-an lo fa a ti wọn fi n pariwo bayii pe ‘‘o to gẹẹ.”

Oyedepo tẹ siwaju pe yoo ṣoro fun awọn agbofinro lati yin wọn nibọn tabi ṣe wọn ni ijanba kankan, nitori ẹhonu ni wọn fi n han, ki i ṣe pe wọn jale tabi kowo jẹ, tabi hu iwa ọdaran kankan.

O ni, “Wahala nla ni yoo da silẹ ti wọn ba pa ẹnikẹni ninu awọn ọdọ to n ṣe iwọde yii, nitori ẹtọ wọn ni wọn n beere fun, ati pe ti eeyan ba le ewure titi to sun un kan ogiri, ko sigba ti ko ni i paju da si eeyan.

“Fun idi eyi, iwọde ti wọn n ṣe yẹn, ohun to tọna ni, bẹẹ lohunkohun ko gbọdọ ṣe wọn, itajẹsilẹ awọn ọdọ, aburu lo maa n fa fun orilẹ-ede.”

One thought on “Wahala nla ni yoo da silẹ ti wọn ba pa ẹnikẹni ninu awọn ọdọ to n ṣe iwọde yii- Oyedepo

Leave a Reply