Wakili ti sọrọ o: Loootọ ni awọn maaluu mi maa n jẹ oko oloko, ṣugbọn mi o ki i ṣe ajinigbe

Isikilu Wakili, ọkan ninu awọn Fulani to ti di ẹru jẹjẹ sawọn eeyan ilu Ayetẹ ati Ibarapa lapapọ lọrun ti sọ pe oun ki i ṣe ajinigbe, loootọ ni oun ni maaluu to pọ, ti awọn maaluu naa si maa n wọ oko oloko ti wọn maa n jẹ nnkan wọn, ṣugbọn oun ko jiiyan gbe ri.

Ọkunrin naa ṣalaye yii fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọse yii, lọdọ awọn ọlọpaa ni Ẹlẹyẹlẹ, niluu Ibadan.  Wakili ni o ṣe diẹ ti ara oun ko ti ya, oun si lọọ gba itọju ni ilu kan ti wọn n pe ni Paraku. O ni aara oun ko ya rara nigba ti awọn OPC de aba oun, awọn obinrin kan ti wọn wa pẹlu oun lasiko naa ni wọn ta oun lolobo pe awọn eeyan naa ti de.

Iskilu ni, ‘Ọjọ kin-in-ni, oṣu yii, ni mo ti kuro nile, ti mo rin irinajo lọ si ilu Paraku to wa ni Ilẹ Olominira Benin. Mo lọ sibẹ lati lọọ gba itọju nitori ara mi ti ko ya. Ọjọ karun-un, oṣu yii, ni mo pada de, ṣugbọn ọjọ meji lẹyin ti mo de, iyẹn ọjọ keje, oṣu yii, ti i ṣe ọjọ Aiku, mo wa nibi ti mo dubulẹ si nitori aiyaara, bẹẹ ni mo gbọ ti awọn obinrin kan n sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ti wa ni aba wa, ati pe wọn di ihamọra wa ni. Emi ni mo sọ fun awọn obinrin naa pe ki wọn tete maa sa lọ, ṣugbọn emi ko le sa nitori aiyaara mi.

‘’Awọn ọkunrin meji ni wọn waa wọ mi jade ninu aba mi nihooho, ti wọn si gbe mi lọ si agọ ọlọpaa. Aimọye igba ni mo daku ko too di pe a de Igbo Ọra, latibẹ ni wọn ti gbe mi wa si ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ niluu Ibadan.

Nigba tawọn akọroyin bi i lori ipa to ko lori ọrọ ijinigbe ati awọn iwa ọdaran to n ṣẹlẹ nilẹ Ibarapa, ọkunrin Fulani naa ni, ‘’Emi o mọ nnkan kan nipa ọrọ ijinigbe o. Ti ẹnikẹni ba ni ẹri to fẹẹ fi silẹ ta ko ohun ti mo sọ yii, ki tọhun bọ sita ko waa sọ ọ. Ẹ lọọ beere ni Ibarapa, mi o ni akọsilẹ iwa ọdaran kankan.

‘’Ogun ọdun ni mo ti lo ni agbegbe naa,  mi o ni akọsilẹ iwa ọdaran kankan. Ti ẹ ba n sọrọ nipa maaluu, mo ni maaluu to pọ, loootọ ni wọn si maa n jẹ wọnu oko oloko, ṣugbọn ni ti ijinigbe, mi o mọ ohunkohun nipa rẹ.

‘’Lati bii ọgbọn ọdun, ko si ọmọ mi kankan ti wọn mu tabi to ni akọsilẹ iwa ọdaran kankan,  ibi to ba ti wu yin lẹ ti le ṣewadii mi, mi o mọ ohunkohun nipa ọrọ ijinigbe. Awọn ọmọ mi meji ni wọn ji gbe lọdun to kọja, ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ni mo fi gba wọn jade. Mi o mọ ohunkohun nipa ijinigbe rara.’’

Bẹẹ ni Wakili ṣalaye fawọn oniroyin

Leave a Reply