Wakilu to purọ pe Boko Haram ti wọlu Imọsan loun fẹẹ fi ṣẹru ba araalu lasan ni

Gbenga Amos, Abẹokuta
Erekere, ere egele ti ọkunrin yii, Wakilu Ogundairo, ṣe niluu Imọsan, Ijẹbu, nipinlẹ Ogun, ti sọ ọ dero ahamọ awọn ọlọpaa bayii o, afaimọ ni ere naa ko si ni i gbe e dewaju adajọ, nitori iwa to hu ọhun ko awọn ọlọpaa ati araalu si ṣibaṣibo gidi, wọn l’ere buruku ni.
Ohun ti a gbọ latẹnu Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ni pe niṣe ni Wakilu ronu ohun ti yoo ṣe ti ko ri, lo ba lọọ sa pamọ sibi kan lọjọ keje, oṣu Kẹfa, o ṣi ikanni Wasaapu rẹ silẹ lori ẹrọ ayelujara, lo ba bẹrẹ si i ka ohun ara rẹ silẹ, bẹẹ lo kegbajare pe eemọ ti wọlu awọn o, o loun ri awọn Boko Haram rẹpẹtẹ, wọn si ti fẹẹ ya bo ilu naa.
Bo ṣe gba rẹkọọdu ọrọ naa tan lo bẹrẹ si i fi i ṣọwọ sawọn eeyan, kia ni ọrọ naa ti n tan kaakiri, lawọn araalu ba ko ọkan soke, ibẹru-bojo mu wọn, awọn kan si ti n sa jade niluu, gbogbo wọn o mọ ibi ti wọn tiẹ le dori kọ, kaluku lo n sa asala fẹmii wọn lai ri nnkan to n le wọn.
Awọn kan lara wọn keboosi lọ si teṣan ọlọpaa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, paṣẹ ki DPO ẹka ileeṣẹ wọn ni Ọbalende, SP Salami Murphy, ko awọn ẹmẹwaa rẹ lọọ koju awọn afẹmiṣofo naa, lai mọ pe irọ lo wa nidii iboosi ti wọn gbọ.
Ṣa, Oyeyẹmi ni abarebabọ wahala awọn ọlọpaa, wọn ko ri Boko Haram kankan nibi ti Wakilu sọ pe wọn wa, awọn ti wọn ri nibẹ ko ju awọn alagbaro ati awọn agbẹ ti wọn jẹ ọmọ ipinlẹ Benue lọ, inu oko wọn lawọn yẹn wa jẹẹjẹ ti wọn n ṣiṣẹ bii akura lọ ni tiwọn.
Awọn ọtẹlẹmuyẹ bẹrẹ iwadii lati mọ ẹni to ko ipaya baraalu bẹẹ, ko si pẹ rara tọwọ fi ba Wakilu. O sọ fun wọn ni teṣan ọlọpaa pe ere loun n ṣe ni toun, oun kan fẹẹ mu wọn nigan-an ni, o loun ko mọ pe ọrọ naa yoo da yanpọn-yanrin bẹẹ silẹ.
Kọmiṣanna ọlọpaa ti ni kawọn ọtẹlẹmuyẹ tubọ ṣiṣẹ iwadii nipa afurasi ọdaran naa, ki wọn too mọ igbesẹ to kan lori ọrọ ẹ.

Leave a Reply