Wamuwamu lawọn agbofinro duro l’Oṣogbo, wọn ni ko gbọdọ si iwọde Iṣọkan ilẹ Yoruba

 Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lọwọlọwọ bayii, ọkẹ aimọye awọn ọlọpaa, sifu difẹnsi, Amọtẹkun, JTF atawọn ọtẹlẹmuyẹ mi-in ni wọn duro ni Freedom Park, to wa ni Old Garage, niluu Oṣogbo, nibi ti awọn oluwọde Iṣọkan ilẹ Yoruba ti fẹẹ ko ara wọn jọ.

Ko si ẹnikankan to le sun mọ wọn nitori kokoko loju gbogbo wọn le.

Idi niyẹn tawọn oluwọde naa fi lọ si abẹ biriiji kan ti wọn n pe ni November 27, nibẹ ni wọn si ti n kora jọ pọ bayii lati bẹrẹ iwọde wọn.

Alaroyegbọ pe bi wọn ṣe n kora jọ l’Oṣogbo naa ni wọn n kora jọ ni Ileefẹ, o si ṣee ṣe ko jẹ pe iwaju aafin Ọọni gan-an ni wọn yoo ti bẹrẹ iwọde naa.

Leave a Reply