Wamuwamu lawọn ọlọpaa duro sawọn ibi kan l’Ekoo, awọn to fẹẹ ṣewọde ni wọn n ṣọ

Jide Alabi

 

 

Lati le pinwọ ikojọpọ tabi ṣiṣe iwọde lati fẹhonu han ni Too-geeti, Lẹkki, l’Ekoo, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, Muyiwa Adejọbi, ti sọ pe awọn ọlọpaa yoo ṣi wa nibẹ titi ti kọmiṣanna yoo fi pinnu lati ko wọn kuro patapata.

Ọjọ Aje, Mọnde yii, ni ileeṣẹ ọlọpaa gbe ikede ọhun jade, bẹẹ lo fi kun un pe yatọ si Too-geeti Lẹkki, awọn ọna mẹrin mi-in lawọn ọlọpaa ti wa kaakiri Eko lati ma ṣe faaye gba ẹnikẹni to ba fẹẹ ṣewọde gẹgẹ bi awọn ọdọ kan ṣe gbero.

Awọn ọlọpaa ti sọ pe awọn ko ni i kuro lawọn agbegbe ọhun titi digba ti Ọgbẹni Hakeem Odumosu, ẹni ti ṣe kọmiṣanna ọlọpaa ba sọ pe ki awọn pada si bareke.

Ṣiwaju si i, ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe oun ko ti i mu ẹnikẹni lọjọ Aje, Mọnde, nitori pe ko ṣeni kan bayii to bọ sita lati ṣewọde.

Lara awọn ibi ti wọn ti ko ọlọpaa da si l’Ekoo niwọnyi; Unity Park, Gani Fawehinmi Park, Orita Ọgọmbọ, Orita Adeniran Ogunsanya atawọn ibomi-in.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, lawọn ọdọ kan jade lati fẹhonu han ninu eyi ti wọn ti mu Ọgbẹni Debọ Adedayọ, ẹni tawọn eeyan si mọ Mr. Macaroni pẹlu awọn ọdọ bii ogoji lori pe wọn jade lati fẹhonu han.

Bẹẹ, ohun ti awọn ọdọ Naijiria n binu si lasiko yii ni bi ijọba ṣe sọ pe oun yoo tun ṣi Too-geeti Lẹkki pada lai ṣeto idajọ to yẹ lori ipakupa ti awọn ṣọja pa awọn ọdọ kan danu logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2020.

Leave a Reply