Waris ti wọn n wa fẹsun ipaniyan ti bọ sọwọ ọlọpaa n’Ilaro

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ninu awọn eeyan ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun n wa fun ẹsun ipaniyan ni ọmọkunrin kan, Ibiyẹmi Waris. Wọn lo ti paayan meji ri, ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ si tun ni. Ni bayii ṣa, wọn ti mu un niluu Ilaro lọjo kẹfa, oṣu kejila, ọdun 2021.

Tẹwọnde ni Waris gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe wi, janduku kan bayii to n daamu wọn niluu Ilaro si tun ni. Ki wọn too ri i mu yii, wọn loun lo pa ẹnikan ti wọn n pe ni Micheal Abiọdun, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ SI.

Ọjọ kejilelogun, oṣu keje, ọdun 2021 yii, ni wọn lo pa Micheal, nigba to si tun di ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, kan naa, Waris tun pa ẹnikan ti wọn pe orukọ ẹ ni Kọla Fagbemi.

Latigba naa lawọn ọlọpaa ti n wa a ki olobo too ta wọn pe Waris wa ni ibuba kan lagbegbe Igboro, n’Ilaro, n ni wọn ba lọọ ka a mọbẹ, wọn si ri i mu laarin awọn janduku, awọn yẹn sa lọ bi wọn ṣe ri ọlọpaa ni.

Lẹyin tọwọ ba a tan, awọn ọlọpaa yẹ ara rẹ wo, wọn ba baagi kan lọwọ Waris Ibiyẹmi.

Ibọn ilewọ ibilẹ kan ni wọn ba ninu baagi ọhun, bẹẹ ni wọn ba ọta ibọn meje ti wọn ko ti i yin nibẹ pẹlu.

Nigba to n jẹwọ ẹṣẹ fawọn agbofinro, Waris sọ pe Ilẹ Olominira Bẹnẹ loun ti ra ibọn toun fi n ṣọṣẹ yii.

Wọn ti taari ẹ sẹka ti wọn ti n ṣewadii awọn ọdaran, gẹgẹ bi CP Lanre Bankọle ṣe paṣẹ.

Leave a Reply