Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Wẹrẹ ni fọto ọhun gori afẹfẹ, iyẹn fọto agba ọjẹ onifuji nni, Alaaji Wasiu Ayinde Marshal, lọsibitu, nibi to ti ṣẹṣẹ pari iṣẹ abẹ.
Ọjọ Satide, ọjọ kẹta oṣu keje yii ni Wasiu Ayinde ju fọto naa sori ayelujara, bo si tilẹ jẹ pe ko sọ pato iru iṣẹ abẹ to ṣe ọhun, sibẹ, niṣe lo n gboriyin fawọn dokita to ṣiṣẹ abẹ naa laṣeye, o loun ko mọ pe bẹẹ ni awọn akọṣẹmọṣẹ dokita wa ni Naijiria yii to.
Eyi lohun ti Mayegun kọ sabẹ fọto rẹ to fi gboriyin fawọn dokita.
‘’Mo dupẹ f’Oluwa, gbogbo ẹ lọ daadaa, iṣẹ abẹ naa si yọri si rere. Loju temi, awọn dokita Naijiria yii lo daa ju, nitori iriri mi pẹlu wọn lonii, ọjọ kẹta oṣu keje ọdun 2021.
‘’Nigba ti dokita mi sọ fun mi pe a lẹ ṣiṣẹ abẹ naa ni Naijiria, mi o ba a jiyan, ṣugbọn mo n ro awọn nnkan kan lọkan nitori mi o ti i ṣe iru aṣẹ-abẹ to lagbara bẹẹ ni Naijiria yii ri.
‘’O ko awọn dokita tọjọ ori wọn ko i goke ṣugbọn ti wọn dara ju jọ, bẹẹ ni wọn si ṣiṣẹ abẹ ọhun’’
Gbogbo awọn dokita to ṣiṣẹ abẹ naa titi dori ẹni to pe ni amugbalẹgbẹẹ rẹ ki wọn too ṣe e lo darukọ pata to si dupẹ lọwọ wọn, bẹẹ lo gba awọn ọmọ Naijiria nimọran pe ohun ti wọn n wa lọ si Sokoto nigba mi-in maa n wa lapo ṣokoto wọn.
Mayegun ni asiko ti to kawọn ọmọ Naijiria mọyi ohun ti wọn ni o.
Ninu fọto mi-in to fi sita lo ti ṣẹṣẹ pari ounjẹ to si n woye, n lawọn eeyan ba n sọ pe bi ara baba ko ba tiẹ ya, bi ẹkọ ba n wọle bii eyi ti ewi n jade, aa jẹ pe alaafia ti de niyẹn.
Wọn ni isinmi lasan ni Wasiu nilo, alaafia ti to o.