Ọlájídé Kazeem
Laafin Olu Itori nipade ọhun ti waye l’Ọjọ̣bọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nibi ti wọn ti yanju wahala to wa laarin Oluaye Fuji, Alhaji Wasiu Ayinde, atawọn ẹgbẹ sọrọsọrọ, eyi to ti n ja ran-in-ran-in nilẹ lati bii ọjọ melooo kan sẹyin.
Nibi ipade ọhun ni Wasiu Ayinde ti bẹ awọn sọrọsọrọ yii, to si fi da wọn loju pe irufẹ iwa buruku ọhun ko ni i ṣẹlẹ ni sakaani oun mọ sẹnikẹni.
Wẹrẹ bayii ni wahala ọhun bẹrẹ laarin ọkunrim olorin fuji yii pẹlu gbajumọ sọrọsọrọ kan to fi ilu Abẹokuta ṣebugbe, Wọle Ṣorunkẹ, ẹni tawọn eeyan tun mọ si MC MURPHY.
Awọn ọmọ ẹyin Wasiu Ayinde ni wọn kọlu u, ti wọn si ṣe e leṣe lọjọ ti Olu Itori n ṣọjọọbi ọgọta ọdun to pe loke eepẹ.
Iṣẹlẹ yii gan an ni wọn lo mu awọn ẹgbẹ sọrọsọrọ paṣẹ fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ wọn kaakiri Naijiria nibi gbogbo ti redio ati tẹlifiṣan ba ti n ṣiṣẹ, ti awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun si n ṣeto nibẹ wi pe wọn ko gbọdọ lo orin e mọ, ati pe awọn yoo tun ko ẹjọ ọhun dele Alaafin Ọyọ, nibi tawọn yoo ti bẹ baba naa pe ko tete rọ ọ loye, nitori ọkunrin naa ko yẹ lẹni ti wọn le maa pe ni Mayegun gẹge bi oye ti Ọba Adeyẹmi Atanda Alaafin fi jẹ.
Bi ọrọ ọhun ṣe wa niyẹn ki awọn eeyan nla nla wọnyi, Mayor Akinpẹlu, gbajumọ oṣere tiata nni, Dele Odule, Ọnarebu Biọdun Akinlade atawọn eeyan nla nla mi-ịn too da si i, ti wọn si ti ba wọn yanju ẹ bayii
O dara ki mayegun Mo ebi re ni E bi Mo yin fun eri okan ti o ni lati Toro a fori Jin in
Ki awon egbe se aforijin fun k1