Wasiu kọ iyawo ẹ silẹ n’Ibadan, o ni imukumu ẹ ti pọ ju

Igbeyawo Abọsẹde Adesọnwo ati ọkọ ẹ, Wasiu, ti daru n’Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, lori ẹsun imukumu ti ọkọ ẹ fi kan an.

Ọkunrin oṣiṣẹ burẹdi yii, Wasiu, lo gba ile-ẹjọ k’ọkọ-k’ọkọ lọ Nile Tuntun niluu Ibadan, nibi to ti rọ Oloye Henry Agbaje, ko da igbeyawo to wa laarin oun ati Abọsẹde, ru nitori ọti amupara ti obinrin naa fẹran lati maa mu, ati pe o tun maa n dunkooko mọ oun ninu ile.

Wasiu sọ pe bi Bosẹ ṣe fẹran lati maa mu ọti, bẹẹ naa lo maa n fun ọmọ awọn ti ko ju ọmọ ọdun mẹta aabọ naa lọti mu, ati pe oun ko mọ wi pe lankẹ-ọmu ni ki oun too gbe e sile bii iyawo.

Ni Agbaje, iyẹn adajọ ile-ẹjọ naa, ba tu igbeyawo wọn ka, bẹẹ lo pa Wasiu, laṣẹ lati maa fun Bọsẹ ni ẹgbẹrun marun-un naira gẹgẹ bi owo ounjẹ fun itọju ọmọ wọn. O ni oun ṣe eyi ki alaafia le jọba ni.

Loju-ẹsẹ ti Adajọ ti gbe idajọ ọhun kalẹ ni Bọsẹ paapaa ti sọ pe o dun mọ oun ninu daadaa nitori pe ilukulu lọkunrin naa maa n na oun, ati pe igbeyawo ọhun paapaa ti yọ lọkan oun patapata.

Leave a Reply