Were bimọ sita gbangba l’Ọrẹ, oun lo gbẹbi ara ẹ Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gbogbo awọn to n gbe lagbegbe kootu Majisireeti to wa niluu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo, lẹnu ya pupọ nigba ti wọn ji laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, ti wọn si ri were kan ti wọn mọ daadaa lagbegbe ọhun to ti bimọ ọkunrin lantilanti funra rẹ ki ilẹ too mọ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, aarin oru lọmọ bẹrẹ si i mu obinrin were ọhun, funra rẹ lo da ọmọ naa bi nigba ti ko rẹni gbẹbi fun un.
Nigba to bímọ ọhun tan, funra rẹ lo ge iwọ rẹ kuro lara olubi, o fi lara akisa to di mọra nu ẹjẹ ara rẹ, bẹẹ lo tun fi nu ẹjẹ ọmọ to bi.
Lẹyin eyi lo ṣẹṣẹ waa fi akisa naa we ọmọ tuntun naa nitori otutu, to si tẹ ẹ sita gbangba nibi tawọn ọlọkada kan ti ba a nigba tilẹ mọ.
Awọn alaaanu kan ni wọn pada gbe obinrin alaaganna ọhun ati ọmọ rẹ lọ sile-iwosan ijọba to wa niluu Ọrẹ fun itọju, nibẹ lo si wa titi di asiko ta a fi n kọ iroyin yii lọwọ.