Were to gun iyawo ẹ ati pasitọ Ridiimu pa, bo ṣe jẹ ree

Ki i ṣe gbogbo eeyan to n fi aṣọ bo ihooho naa ni ọpọlọ wọn pe, awọn ẹlomi-in wa to jẹ aaganna wa lara wọn, ṣugbọn teeyan ko le tete mọ, afawọn ẹni to ba sun mọ iru wọn nikan. Iru ẹ ni tọkunrin ti wọn pe orukọ ẹ ni Obum, nipinlẹ Imo, ẹni to gun iyawo ẹ pa pẹlu pasitọ ijọ Ridiimu to laja oun atiyawo naa, ko too di pe awọn aye lu oun naa pa lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii.

Ohun to ṣẹlẹ gan-an gẹgẹ bawọn eeyan tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe ṣalaye ni pe, Obum bẹrẹ si i ba iyawo torukọ ẹ n jẹ Ogechi ja ninu palọ wọn, niṣe lo yọ ọbẹ si i pẹlu ọmọ ọdun kan tiyẹn n tọ lọwọ, o si bẹrẹ si i gun iyawo rẹ yii lọbẹ. O ni obinrin naa lo n ṣe oun, ati pe o fẹẹ pa ọmọkunrin kan ṣoṣo tawọn jọ bi lati ọdun 2016 tawọn ti fẹ ara wọn.

Obum yii ko gbadun gẹgẹ bawọn eeyan rẹ ṣe wi, wọn ni aisan ọpọlọ n yọ ọ lẹnu, ṣugbọn ki i ṣe pe o ja ọja, ko si ki i ṣe gbogbo igba lo maa n sọ ọ wo, awọn kan si tilẹ sọ pe o ṣẹṣẹ bẹrẹ ni. Wọn ni nigba ti kinni naa ba sọ ọ wo naa lo maa n huwa ẹni ti ọpọlọ rẹ dorikodo.

Bo ṣe tun waa gbe iṣe rẹ de si iyawo rẹ lo jẹ kawọn to wa nitosi gbiyanju lati gba obinrin naa lọwọ rẹ, nigba ti wọn gbọ to n ke irora, iyẹn nile wọn to wa Umuokoto, Umudibia, Owerri, nipinlẹ Imo.

Ogechi bẹrẹ si i pariwo pe kawọn eeyan waa gba oun kalẹ lọwọ ọkọ oun, o ti fẹẹ gun oun pa. Awọn eeyan pe jọ loootọ lati gba obinrin yii atọmọ ọdun kan to n tọ lọwọ, ṣugbọn niṣe ni Obum bẹrẹ si i halẹ pe bi ẹnikan ba fi le sun mọ oun tabi to gbiyanju lati gba iyawo oun silẹ, oun yoo gun tọhun pa ni, n lawọn eeyan ba n sa sẹyin.

Afi pasitọ Onyekuru to ṣe ọkan akin, jẹẹjẹ rẹ lo si n bọ lati ipade kan to lọ lagbegbe naa, oun lo gbiyanju to gba Ogechi atọmọ rẹ silẹ ki ọkunrin yii maa baa gun wọn pa, awọn eeyan si gbe iyawo naa lọ sọsibitu. Bi pasitọ yii ṣe gba obinrin naa silẹ lọwọ ọkọ ẹ to pẹyinda ni ọkunrin alarun ọpọlọ yii fọbẹ gun un latẹyin, n lẹjẹ ba bo pasitọ, o si ṣubu lulẹ lai lagbara mọ.

Gbogbo eeyan n gbiyanju lati mu Obum, niṣe legungun rẹ n ran si i. Koda, nigba tawọn ọlọpaa kan kọja ti wọn gbiyanju lati mu un walẹ, niṣe lo tun n ranju pẹlu ọbẹ naa lọwọ, iyẹn lo jẹ kawọn ọlọpaa naa yinbọn mọ ọn lẹsẹ, nigba naa lo si ṣẹṣẹ jokoo jẹẹ. Awọn eeyan tinu rẹ n bi ko foju ire wo o bo ṣe jokoo kalẹ, wọn da iya jọ fun wọn si bẹrẹ si i lu u, lilu naa pọ debii pe ọsibitu lo balẹ si.

Wọn gbe pasitọ Onyekuru ati Obum to gun un lọbẹ lọ sọsibitu, ṣugbọn ibẹ ni pasitọ dagbere faye si, Obum naa si dero ọrun latari bawọn eeyan ṣe dawọ jọ lu u, ati ọgbẹ ibọn to wa lẹsẹ rẹ. Eyi to ba ọrọ naa jẹ ni ti Iyawo Obum, Ogechi, ti wọn loun naa pada ku ni, latari ọgbẹ buruku ti ọkọ rẹ ti da si i lara.

Aarẹ ipade agbegbe Umuokoto ni Imo, Ọnarebu Charles Anozie, to fidi iṣẹlẹ aburu yii mulẹ sọ pe bo ṣe ṣẹlẹ ree, o si ba gbogbo awọn lọkan jẹ pe iku ṣoro bẹẹ lawujọ awọn lọjọ kan ṣoṣo.

Leave a Reply