Wọn ni eeyan meje lawọn ọlọpaa yinbọn pa l’Ogbomọṣọ, wọn tun ti rọ ọpọ ọdọ da satimọle n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti ṣeleri atilẹyin rẹ fawọn to n pe fun ki opin de ba SARS, iyẹn ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale. O ni kijọba apapọ tete fopin si awọn oṣiṣẹ alaabo ọhun nitori iya ti wọn fi n jẹ araalu ju anfaani ti wọn n ṣe fun wọn lọ.

Lasiko to n ba awọn to n fẹhonu han sọrọ ni sẹkiteriati ijọba ipinlẹ naa to wa l’Agodi, n’Ibadan, Gomina Makinde, ẹni ti Ọnarebu Debọ Ogundoyin ti i ṣe abẹnugan ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ,  pẹlu diẹ ninu awọn igbimọ alaṣẹ ijọba naa kọwọọrin pẹlu ẹ, ṣeleri pe gbogbo igbesẹ to yẹ loun ti gbe lati ri i pe wọn ko yinbọn pa ẹnikẹni mọ lasiko ti wọn ba n ṣewọde tako ohun ti ko dun mọ wọn ninu nitori ẹtọ wọn ni lati sọ nnkan to n dun wọn lọkan sita.

Bakan naa lo fi awọn ọdọ oniwọọde naa lọkan balẹ pe gbogbo awọn olufẹhonu han ti awọn ọlọpaa ti rọ dà satimọle pata loun yoo ri i pe oun yọ jade.

Ṣe lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja la gbọ pe awọn ọlọpaa yinbọn pa eeyan ti ko din ni meje niluu Ogbomọṣọ, lasiko iwọde ti wọn ṣe pe kijọba fopin si awọn ọlọpaa SARS.

Ṣaaju ni igbakeji gomina ipinlẹ naa, Ẹnjinnia Rauf Ọlaniyan ti gbiyanju lati pẹtu si awọn olufẹhonu han yii ninu, ṣugbọn ti wọn yari kanlẹ, wọn ni gomina gan-an lawọn fẹẹ ri.

Gẹgẹ bi Gomina Makinde ṣe sọ, “Ṣaaju asiko yii lemi paapaa iba ti wa pẹlu yin, Ogbomọṣọ ti mo lọ lo fa a, mo lọ sibẹ lati lọọ ṣabẹwo si awọn mọlẹbi awọn eeyan to padanu ẹmi wọn nibi iwọde to waye l’Ogbomọṣọ ni Satide to kọja ni.

“Labẹ ofin orileede yii, ẹtọ yin ni lati fẹhonu han lati beere ẹtọ yin. Ṣugbọn mo bẹ yin lati ma ṣe gbe iwọde yin gba ilana jagidijagan nitori idagbasoke kan ko le waye lawujọ ti idarudapọ ba ti n waye.

“Gbogbo ara ni mo fi wa pẹlu yin. Mo ti ba ọga agba ọlọpaa (ipinlẹ Ọyọ) sọrọ. Mo si fi da yin loju pe gbogbo awọn to ti wa latimọle lori iwọde ti ẹ n ṣe yii la maa gba beeli wọn.”

Lẹyin ti awọn ọdọ kaakiri orileede yii ti fi gbogbo ọsẹ to kọja ṣe iwọde lati rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ lati fopin si awọn ọlọpaa SARS, ti Aarẹ orileede yii, Ọgagun Muhammadu Buhari, ati Adamu Muhammed ti i ṣe ọga agba awọn ọlọpaa nilẹ yii si ti ṣeleri pe ko ni i si ohun to n jẹ SARS lara awọn ọlọpaa mọ, sibẹ  awọn ọdọ kaakiri igboro Ibadan tun tẹsiwaju ninu iwọde wọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ana, wọn ni ọpọ ileri bẹẹ nijọba apapọ ti ṣe nipa SARS ṣaaju ṣugbọn ti ayipada kankan ko tori ẹ waye.

Ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọdọ lo ya soju titi kaakiri igboro Ibadan fun iwọde ọhun, ti wọn si da sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ silẹ lọpọlọpọ awọn ọna to ṣe koko nigboro ilu naa.

Niṣe lawọn oluwọde yii di ẹnu ọna sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọ pa, nigba ti oriṣii awọn ikọ oluwọde meji pade nibẹ lẹẹkan ṣoṣo, Awọn ikọ oluwọde ti wọn bẹrẹ tiwọn ni Iwo Road gba ọna ile ijọba l’Agodi wọle, nigba ti awọn to kóra jọ siwaju Fasiti Ibadan (UI) lati bẹrẹ iwọde ọhun gba Bodija wọle, gbogbo wọn ba fabọ siwaju ileeṣẹ ijọba l’Agodi.

Iwọde ti wọn ṣe ni Iwo Road, n’Ibadan, lo gbẹnu tán, nitori awọn to ṣewọde nibẹ ko din lẹgbẹrun mẹta eeyan, sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ti wọn da silẹ nibẹ ko si mọ lori awọn oni nnkan irinsẹ nikan, tipatipa lawọn to n fẹsẹ rin paapaa fi n rọna kọja.

Ko jọ pe iru iwọde bẹẹ ṣẹlẹ ri n’Ibadan. Awọn ti àárẹ̀ ba ti mu laarin awọn olufẹhonu han yii, kaka ki wọn pada sile wọn jẹẹjẹ, niṣe ni wọn n wa ibi kan nitosi lọọ sinmi, ti wọn si tun n pada sibi ifẹhonu han wọn ti ara wọn ba ti mokun.

Ọkan ninu awọn oluwọde naa, ẹni to kọ lati darukọ ẹ fakọroyin wa ṣalaye pe “Ṣe ẹ ri i pe ọlọpaa kankan ko jade si wa lonii, nigba ti Gomina Makinde wa niluu Akurẹ fun amojuto eto idibo ti wọn ṣe lọjọ Satide lo pe ọga wọn pe wọn ko gbọdọ koju awọn to ba n ṣewọde mọ.

 

“Ta a ba wo awọn SARS yii, loootọ ni wọn ni iwulo tiwọn, ṣugbọn ta a ba da iṣẹ ti wọn n ṣe si mẹwaa, aburu wọn lo ko mẹjọ nibẹ.  Bii apẹẹrẹ, ti wọn ba fura pe ọmọ Yahoo lẹnikan, wọn aa fi tipatipa gbowo lọwọ ẹ, lẹyin naa ni wọn maa pa a danu ko ma baa pada tu wọn laṣiiri lọjọ iwaju. Eeyan ti wọn ti ṣe bẹẹ pa danu ko niye.”

Leave a Reply