Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọrọ awọn arinrianjo ti wọn ji gbe lọna Eruwa la ṣi n sọ ta a ti i dakẹ ti awọn ajinigbe tun fi ṣe bẹbẹ mi-in lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja pẹlu bi wọn ṣe ji ọkunrin kan to n jẹ Fẹmi Ọla Abraham gbe labule ti wọn n pe ni Aba Konko, nitosi ilu Ayetẹ, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ.
Abraham atawọn meji mi-in ti wọn n jẹ Ọlawumi Michael ati Jẹjẹ Abiọla l’ALAROYE gbọ pe wọn jọ ririnajo naa, ṣugbọn to jẹ pe baba ẹni ọdun marundinlaaadọta (45) yii nikan ni nnkan ko ṣẹnuure fun nigba ti ori ko awọn meji yooku yọ.
Latilu Ibadan la gbọ pe wọn ti n bọ ki awọn ajinigbe ti wọn to mẹwaa niye too yọ si wọn lọgangan ori afara odo kan ti wọn n pe ni Oke-Ari-n-sa, labule Konko, ni nnkan bii aago meje aabọ aarọ ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹrin, 2021 yii.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, inu odo lọkunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29) to n jẹ Abiọla, pẹlu Michael to jẹ ẹni ọdun mejilelọgbọn (32) bẹ si, ti wọn si ba ibẹ sa lọ nigba ti awọn ajinigbe ọhun ya bo wọn tibọntibọn. Baba ẹni ọdun marundinlaaadọta aarin wọn nikan ni ko ribi sa mọ awọn ẹruuku lọwọ ti wọn fi gbe e lọ sinu igbo rere.
Bo tilẹ jẹ pe akitiyan wa lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lọdọ awọn agbofinro ko seso rere pẹlu bi awọn ipe akọroyin yii ko ṣe wọle sori aago DSP Adewale Ọṣifẹṣọ ti i ṣe agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, sibẹ, ọmọ ilu Ayetẹ kan, Sulaiman Ademọla, fidi ẹ mulẹ pe awọn ọlọpaa ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, wọn si ti bẹrẹ iṣẹ lati ri i pe wọn yọ ẹni ti wọn ji gbe naa kuro nigbekun awọn ajinigbe ọhun laaye.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Nibi ti ọrọ aabo de duro lagbegbe yii, ko sẹni to n da lọ sinu oko mọ nitori wahala awọn Fulani atawọn ajinigbe. Ṣugbọn bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, awọn ọlọpaa ti gbakoso awọn igbo to wa lagbegbe yii. Awọn ọlọpaa bii ọgbọn (30) lemi atawọn eeyan mi ta a jọ n dẹgbẹ kiri pade ninu igbo nirọle ọjọ Ẹti. Iyẹn gan-an lo jẹ ka tete pada sile nitori a ko fẹẹ fi tiwa di wọn lọwọ iṣẹ wọn.”