Wọle ati Saheed ko sakolo ọlọpaa, ole ni wọn n ja loju popo l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Awọn gende meji yii, Saheed Ojo, ẹni ọdun mọkanlelogun, ati Oluwọle Khalid, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ti wa lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, bayii, iṣẹ ole to n ja owo ati foonu gba loju popo ni wọn n ṣe tọwọ fi tẹ wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa Eko, ẹka ayara-bii-aṣa (Rapid Response Squard) lo fọrọ iṣẹlẹ yii ranṣẹ s’ALAROYE, wọn lopin ọsẹ to kọja yii lawọn agbofinro mu awọn afurasi ọdaran mejeeji yii lọna marosẹ agbegbe Iyana Oworo si too-geeti atijọ ni Ketu, nipinlẹ Eko.

Ki i ṣawọn nikan lo n ṣiṣẹẹbi ọhun, wọn ni wọn pọ, ṣugbọn bawọn ọlọpaa ṣe bọọlẹ lati wadii ohun to n ṣẹlẹ lawọn alọ-kolohun-kigbe ẹda naa bẹ danu lọkọọkan, wọn sa lọ, ẹni meji pere ni wọn ri mu.

Wọn ni niṣe lawọn afurasi mejeeji yii n tu igbo ẹba ọna, nibi ti wọn n tọju awọn dukia ti wọn ja gba lọwọ awọn ero ọkọ ati onimọto si lọwọ ni wọn fi mu wọn.

Wọn ba awọn foonu, ọbẹ aṣooro, egboogi oloro ti wọn fura pe igbo ni atawọn ẹru ofin mi-in nibi ti wọn ti mu wọn.

Ṣugbọn ni teṣan, nigba tawọn ọlọpaa n bi wọn leere ọrọ, awọn mejeeji yii lawọn ki i ṣe ole o, wọn ni igbo lawọn n fa ni tawọn, tori awọn o fẹ ki oorun kun awọn loru ni, ibi tawọn ti n fagbo ni wọn ti m’awọn.

Ṣa, iwadii ti bẹrẹ, wọn si ti n wa awọn ẹlẹgbẹ wọn to sa lọ, wọn ni gbogbo wọn maa fimu kata ofin.

Leave a Reply