Wolii Eli-Wakuku ati babalawo ẹ ti wọn jọ n ṣowo agbari oku ti dero ẹwọn ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Oludasilẹ ijọ St. Moses Orimọlade Cherubim and Seraphim to wa niluu Ilọrin, Wolii Gabriel Josaya tawọn eeyan mọ si Eli-Wakuku ati babalawo rẹ, Gabriel Moyọsọrẹ, ti rẹwọn ọdun mẹrin he lọjọ Aje, Mọnde, ana, fun ẹsun pe wọn n ta ẹya ara eeyan.

Adajọ Mohammed Ibrahim tile-ẹjọ magisreeti kan to wa niluu Ilọrin lo paṣẹ naa. O ni ọdaran naa ko lanfaani si sisan owo itanran.

Eli-Wakuku pẹlu babalawo to maa n ta agbari atawọn ẹya ara eeyan mi-in fun, Moyọsọrẹ, naa ni wọn jọ wa nile-ẹjọ fun idajọ lẹyin bii ọdun mẹta ti igbẹjọ ti n waye lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Iwadii awọn ọlọpaa fi han pe Wolii Josaya maa n rapala wọ itẹku nibi to ti n hu awọn agbari oku to si n ta ọkọọkan ni ẹgbẹrun mẹjọ naira fun onibaara rẹ.

Lasiko iwadii naa awọn ọlọpaa ba agbari oku nile Moyọsọrẹ ti n ṣe babalawo to n ba Josaya ra ọja, iyẹn si jẹwọ bi ọrọ kinni ọhun ṣe jẹ.

Ninu ẹri oluwadii ileeṣẹ ọlọpaa, Peter Ibiyẹmi, o ṣalaye fun ile-ẹjọ pe Josaya jẹwọ pe agbari oku bii ọgọrun-un meji loun ti hu lori itẹku musulumi to wa lagbegbe Osere, niluu Ilọrin toun si ti lu ta.

Ibiyẹmi ni lati ọdun 2009 ni ọdaran naa ti bẹrẹ owo tita agbari oku, aarin oru lo maa n saaba lọ, koda oun nikan lo maa n da lọ sibẹ.

O tẹsiwaju pe ẹgbẹrun mẹwaa naira ni Josaya maa n fun ẹṣọ itẹku naa ni gbogbo igba to ba ti lọọ hu ọja to n ta, eyi lo maa n fun un lanfaani lati farabalẹ hu iye agbari oku to ba wu u lai si ẹni to maa yẹ lọwọ wo.

Ṣugbọn agbẹjọro ọdaran naa, Ibrahim Olojoku, ni awọn ọlọpaa lo fipa mu onibaara oun lati sọ gbogbo ohun ti wọn lo sọ naa.

Olojoku ni oun foju ri ibi ti wọn ti na an ti wọn si ni ko gba pe loootọ loun jẹbi ẹsun naa.

Agbẹjọro ọhun ni oun yoo ba onibaara oun sọrọ boya awọn yoo pẹjọ ko-tẹmi-lọrun tako idajọ ile-ẹjọ naa.

Leave a Reply