Wolii awọn onirọ ni Lai Muhammed, ojumọ kan, irọ kan ni-Aṣofin Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gbọn mi si i, omi o to o, to n ba ẹgbẹ oṣelu APC, ẹka ti ipinlẹ Kwara, finra si n tẹsiwaju ni o, awọn aṣofin ipinlẹ naa pepade apero lọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, lori awọn ọrọ kobakungbe ti Minisita fun eto ibanisọrọ ati aṣa nilẹ yii, Lai Muhammed, sọ si Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRasaq, wọn ni Lai Muhammed, wolii awọn onirọ ni, bi ilẹ ọjọ kan ba ti mọ, anfaani ọna irọ miiran lo ṣi silẹ fun un.

Nibi ipade apero ọhun to waye lọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, ni awọn asofin naa ti sọ pe gbogbo ọrọ to n tẹnu minisita jo bii ibọn lo jẹ pe irọ funfun balau ni, wọn ni iroyin tẹ awọn lọwọ pe, Lai Muhammed sọ pe oun ni oun san owo ti gbogbo awọn ọmọ aṣofin mẹrẹẹrinlelogun fi ṣe ipolongo eto idibo, nibi idibo gbogbogboo to waye lọdun 2019, awọn asofin ni irọ to jinna si ootọ ni.

Wọn ni gbogbo ọrọ ti Lai sọ lọjọ Abamẹta, Satide to lọ nipa gomina, irọ ni, ati pe ko yẹ ki ọrọ minisita yii jẹ tuntun leti awọn eeyan tori pe irọ lo yan laayo lati ọjọ aye rẹ. Wọn waa rọ gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara lati ma ṣe tẹle ọrọ ẹnu Lai, tori pe irọ lo maa n jade lẹnu rẹ. Bakan naa, wọn rọ minisita lati gbaju mọ iṣẹ ti ijọba apapọ gbe le e lọwọ, ko fi gomina lọrun silẹ.

Leave a Reply

//eephaush.com/4/4998019
%d bloggers like this: