Wọn ṣebura fawọn adajọ mẹjọ nile-ẹjọ to ga ju lọ

Jide Alabi

Adajọ agba lorilẹ-ede yii,  Adajọ Tanko Muhammad, ti bura fun awọn adajo mẹjo mi-in bayii lati darapọ mọ awọn mejila ti wọn ti n jokoo ṣedajọ nile-ẹjọ to ga julọ nilẹ wa.

Awọn adajọ agba fun ile-ẹjọ to ga julọ ni Naijiria bayii niwọnyi; Lawal Garba; Helen Ogunwumiju; Abdu Aboki; ati M. M. Saulawa.

Awọn yooku ni Adajọ Adamu Jauro; Samuel Oseji; Tijani Abubakar ati Emmanuel Agim.

Awọn mẹjẹẹjọ yii ni Adajọ-agba Tanko Muhammad,  ṣebura fun, eyi si sọ gbogbo adajọ ile-ẹjọ to ga julọ ni Naijiria di ogun bayii.

 

Leave a Reply