Wọn ṣebura fun Akeredolu sipo gomina Ondo lẹẹkeji

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Ẹsẹ o gbero ni gbọngan asa igbalode Doomu to wa loju ọna Igbatoro, l’Akurẹ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lasiko ti wọn n ṣayẹyẹ ibura sipo gomina ẹlẹẹkeji fun Gomina Rotimi Akeredolu ati Igbakeji rẹ tuntun, Ọnarebu Lucky Aiyedatiwa.

Nnkan bii aago mẹsan-an aarọ lawọn eeyan ti kun inu gbọngan ọhun bamubamu, ti wọn si n duro de asiko ti eto fẹẹ bẹrẹ.

Igbakeji gomina ni wọn kọkọ bura fun ki ọpọn too sun kan Gomina Akeredolu funra rẹ.

Ninu ọrọ akọsọ Arakunrin lẹyin ti adajọ agba nipinlẹ Ondo, Onidaajọ Oluwatoyin Akeredolu, bura fun un tan lo ti ṣeleri lati tẹsiwaju nínú ṣiṣẹ sin awọn eeyan ilu.

Akeredolu ni bo tilẹ jẹ pe iṣẹlẹ arun Korona ko ba eto ọrọ aje ipinlẹ Ondo, leyii to mu awọn idiwọ diẹ ba awọn iṣẹ idagbasoke to yẹ ko waye lọdun mẹrin akọkọ, sibẹ, o ni oun ti ṣetan lati wa gbogbo ọna tawọn araalu yoo fi tẹsiwaju lati maa jẹ anfaani ijọba tiwa-n-tiwa ni saa kejì oun lori aleefa.

Gomina ni ohun ti yoo jẹ afojusun oun ni saa keji ni idagbasoke eto ẹkọ, eto ọgbin, ipeṣe iṣẹ ati titọju awọn to wa ni igberiko.

Lara awọn eeyan jankan jankan to wa nibi eto ibura wọle naa ni: Oloye Bọla Tinubu, Bisi Akande, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, Gomina ipinlẹ Ọsun, Alaaji Gboyega Oyetọla, Gomina ipinlẹ Ekiti to tun jẹ alaga awọn gomina patapata, Kayọde Fayẹmi, Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki atawọn eeyan mi-in.

Leave a Reply