Wọn ṣeeṣi san miliọnu meji s’akaunti Adetunji, lo ba na gbogbo ẹ, adajọ ti ju u sewọn

Stephen Ajagbe, Ilorin

A ṣe oootọ lọrọ tawọn eeyan maa n sọ pe ifa a maa fa ni lapo ya nigba mi-in. Bẹẹ gẹlẹ lọrọ ri fun dẹrẹba ẹni ọdun marundinlaaadọta kan, Adetunji Tunde Oluwaṣẹgun, ẹni to ṣadeede ri miliọnu meji naira to wọnu akanti rẹ, to si ku owo naa na.

Nigba tajọ EFCC wọ ọ lọ sile-ẹjọ giga kan niluu Ilọrin, adajọ ni ki ọkunrin naa lọọ ṣẹwọn ọdun meji gbako nitori iwa ole ati aini ootọ to hu naa.

Adajọ Sikiru Oyinloye to paṣẹ naa ni ọdaran ọhun gbọdọ da gbogbo owo naa pada fun ẹni to ni i ki ọdun meji ẹwọn rẹ to n ṣe too pe.

Arabinrin Ṣhẹrifat Ọmọlara Sanni ni wọn lo ṣeeṣi san miliọnu meji naira sinu akanti GTB; 0008383333, ti Adetunji n lo, laarin oṣu keje si ikẹjọ, ọdun 2020, ṣugbọn dipo ko jẹ ki banki rẹ mọ, ṣe lo bẹrẹ si ni na an titi to fi pari ẹ.

Ọdaran naa ni loootọ loun jẹbi nigba tile-ẹjọ ka ẹsun rẹ si i leti.

Adajọ Oyinloye ni niwọngba to ti jẹwọ pe oun jẹbi, ko lọọ ṣẹwọn, ko le baa jẹ arikọgbọn fun awọn to ba n hu iru iwa bẹẹ.

 

Leave a Reply