Won ṣi n wa Aafaa Mọshood to lu ọmọ kewu rẹ daku n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Olukọ imọ Kuraani kan, Aafaa Mọṣhood, ti di ẹni ti wọn n wa bayii latari bo ṣe lu akẹkọọ rẹ kan daku, to si sa lọ patapata lagbegbe Ogidi, niluu Ilọrin.

ALAROYE gbọ pe ẹsun ti Mọṣhood fi kan akẹkọọ naa ni pe o ji kolo toun fi owo pamọ si.

Nigba ti wọn ni aafaa naa gbọ pe ọrọ ọhun ti de ọfiisi ajafẹtọọ araalu, National Human Right Commission, kia lo kan lugbẹ, titi di ba a ṣe n sọ yii, ko sẹni to mọ ibi to sa lọ.

Akẹkọọ ọmọ ọdun mẹrinla ọhun ni wọn sọ pe aafaa na ni koboko ni aimọye igba. Lẹyin to na tiẹ tan lo tun paṣẹ fawọn ọmọ ileekewu yooku ti wọn n lọ bii ọgọta, lati maa na an ni koboko mẹwaa-mẹwaa, titi tiyẹn fi daku rangbandan.

Ṣe ni wọn ni aafaa naa ni ki akẹkọọ ọhun sun sori tabili, o si ni kawọn rigipa kan gba ọwọ ati ẹsẹ rẹ mejeeji mu titi ti wọn fi lu u doju iku.

Aṣoju ajọ to n ja fẹtọọ araalu, Amọfin Ahmed Rufai, ni ọmọ naa ṣi wa nilewosan, nibi to ti n gba itọju, igbiyanju si n lọ lati ri aafaa naa mu.

 

 

Leave a Reply