Wọn ṣi n wa awọn arinrin-ajo tí wọn ji gbe l’Ajọwa Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Apapọ awọn ẹsọ alaabo ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ igbesẹ lati ṣawari awọn arinrin-ajo kan ti wọn ji gbe laarin Ajọwa si Akunnu Akoko lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Ṣe ni wọn deedee ba bọọsi ambulansi kan laarin ọna marosẹ Ajọwa si Akunnu, èyí tí wọn ko pana rẹ, bẹẹ ni wọn si tun ṣi gbogbo ilẹkun rẹ silẹ lai si ẹnikankan ninu rẹ.

Kiakia lawọn eeyan agbegbe ọhun ti mọ pe o ṣee ṣe ko jẹ awọn ajinigbe to n ṣoro bii agbọn ni wọn da wọn lọna, ti wọn si fipa ko gbogbo awọn ero ọkọ naa wọnu igbo lọ.

Eyi lo ṣokunfa bawọn ẹsọ alaabo, ninu eyi ta a ti ri, awọn sọja, ọlọpaa, fijilante ati ẹsọ Amọtẹkun ṣe ko ara wọn jọ, ti wọn si n fọ gbogbo inu igbo to wa lagbegbe ibi tiṣẹlẹ ọhun ti waye lati ṣawari awọn ti wọn ji gbe naa lọnakọna bo tilẹ jẹ pe akitiyan wọn ọhun ko ti i so eso rere lasiko ta a fi n kọ iroyin yii lọwọ.

Ko sẹni to ti i le sọ ní pato iye ati iru awọn eeyan tawọn ajinigbe ọhun ji gbe lọ, bẹẹ ni a ko ti i ri i gbọ pe wọn kan si ẹbi ẹnikẹni ninu wọn.

Ọdọ awọn ṣọja to n peṣe aabo fawọn arinrin-ajo lagbegbe Ajọwa, ni wọn gbe ọkọ ambulansi ti wọn ri naa pamọ si nigba ti akitiyan awọn ẹsọ alaabo ṣi n tẹsiwaju lati doola awọn ti wọn ji gbe ọhun ni gbogbo ọna.

 

Leave a Reply