Wọn ṣi n wa babalawo tawọn ọtẹlẹmuyẹ gbe lọ n’Ikẹrẹ-Ekiti

Taofiq Surdiq, Ado-Ekiti

Inu idaamu ni awọn ẹbi gbajugbaja babalawo kan n’Ikẹrẹ-Ekiti, Ọgbẹni Dada Ifasootọ, wa bayii latigba ti awọn kan ti wọn wọṣọ ologun ti waa gbe e lọ lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, titi ta a si fi pari iroyin yii, wọn o ti i ri i.

Iya to bi Dada, Beatrice Ifasootọ, lo kegbajare faye lẹyin iṣẹlẹ naa. O ni awọn kan ti wọn wọṣọ ologun, ti wọn si dihamọra ni wọn wọle waa gbe ọmọ oun lalẹ ọjọ naa, ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ.

Mama sọ pe ohun ti awọn ologun naa sọ fọmọ oun ni pe awọn fẹẹ gbe iṣẹ kan fun un, awọn si fẹẹ ba a dunaa-dura lori rẹ, nitori naa, ko maa ba awọn kalọ.

Koda, mọto awọn ologun lawọn to waa gbe e naa gbe wa gẹgẹ bi iya ṣe wi, nọmba idanimọ to wa lara ọkọ naa si jẹ ti olu ilu ilẹ wa, Abuja.

Gẹgẹ bawọn eeyan ṣe wi, babalawo to gbona gidi ni Dada Ifasootọ ti wọn ni ọjọ ori ẹ ko ju ọgbọn ọdun lọ, ṣugbọn bi wọn ṣe waa gbe e lọ yii ko ye ẹnikẹni.

Iya rẹ sọ pe ọmọ oun ko ba ẹnikẹni daṣẹ pọ, oun ko si ro pe o ṣẹ ẹṣẹ kan to fi di pe wọn waa gbe e lai jẹ ki ẹnikẹni tẹle e, tawọn ko si ti i mọ ibi to wọlẹ si titi dasiko yii.

DSS ni Iya Dada sọ pe wọn kọ si ara aṣọ awọn to waa gbe ọmọ oun lọ, o ni awọn eeyan ti wọn le kawe ni wọn sọ bẹẹ foun. Mama ẹni aadọrin ọdun naa sọ pe eyi to wu ko tiẹ jẹ, ki wọn ṣaa ba oun da ọmọ oun pada laaye loun n beere, kawọn ologun naa ma ka oun leyin ọọkan, nitori ọmọ oun ki i ṣe ole, babalawo ni.

“Ẹṣẹ wo lọmọ mi le ṣẹ ti wọn fi maa waa mu un lai sọ ibi ti wọn ti waa gbe e?

“Mo n bẹ awọn ọmọ Naijiria ki wọn da si ọrọ yii, ki wọn ran mi lọwọ lati wa ọmọ mi jade ni ibikibi to ba wa” Bẹẹ ni Iya Dada wi.

Leave a Reply

//eephaush.com/4/4998019
%d bloggers like this: