Wọn ṣi n wa Dokita Adeogun atawọn osiṣẹ rẹ meji ti wọn ji gbe n’Idoani

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni wọn ṣi n wa ọga awọn dokita ile-iwosan ijọba to wa n’Idoani, Dokita Olufẹmi Adeogun, atawọn meji mi-in ti wọn ji gbe lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii.

Awọn ajinigbe naa la gbọ pe wọn da ọkọ tawọn eeyan ọhun wa ninu rẹ duro lasiko ti wọn de ibi ti ọna ti bajẹ lagbegbe Iwani/Idoani, ti wọn si fipa ji awọn mẹtẹẹta gbe sa lọ.

Ori lo ko awakọ to gbe awọn oṣiṣẹ yii lọjọ naa pẹlu bawọn oniṣẹẹbi ọhun ṣe yinbọn lu u nibi to ti n gbiyanju ati sa mọ wọn lọwọ.

Ọkunrin yii ṣi wa nileewosan kan to ti n gba itọju ni gbogbo asiko ta a fi n kọ iroyin yii lọwọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, ni igbesẹ ti bẹrẹ lori bi awọn ti wọn ji gbe ọhun yoo ṣe di riri pada laipẹ rara.

About admin

Check Also

Awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori tiṣa to na ọmọleewe to fi ku l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko Afaimọ ni tiṣa ti wọn porukọ rẹ ni Ọgbẹni Stephen yii ko …

Leave a Reply

//ugroocuw.net/4/4998019
%d bloggers like this: